Isaiah Sọtẹ́lẹ̀ Nípa Ìkọlù Àwọn Ará Asiria (continued)
Àsọtẹ́lẹ̀ Isaiah nípa bí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Asiria yóò ṣe kọlu Palestini.
715 ṣáájú ìbí Kristi
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)
1 Èèkàn kan yóò sọ láti ibi kùkùté Jese,
láti ara gbòǹgbò rẹ̀ ni ẹ̀ka kan yóò ti so èso.
2 Ẹ̀mí Olúwa yóò sì bà lé e,
ẹ̀mí ọgbọ́n àti ti òye,
ẹ̀mí ìmọ̀ràn àti ti agbára,
ẹ̀mí ìmọ̀ àti ti ìbẹ̀rù Olúwa.
3 Òun yóò sì ní inú dídùn nínú ìbẹ̀rù Olúwa.
Òun kì yóò ṣe ìdájọ́ pẹ̀lú ohun tí ó fi ojú u rẹ̀ rí,
tàbí pẹ̀lú ohun tí ó fi etí i rẹ̀ gbọ́,
4 ṣùgbọ́n pẹ̀lú òdodo ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn aláìní,
pẹ̀lú òtítọ́ ni yóò ṣe ìpinnu
fún àwọn aláìní ayé.
Òun yóò lu ayé pẹ̀lú ọ̀pá tí ó wà ní ẹnu rẹ̀,
pẹ̀lú èémí ẹnu rẹ̀ ni yóò pa àwọn ìkà.
5 Òdodo ni yóò jẹ́ ìgbànú rẹ̀
àti òtítọ́ ni yóò ṣe ọ̀já yí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ká.
6 Ìkookò yóò sì máa bá ọmọ àgùntàn gbé,
ẹkùn yóò sì sùn ti ewúrẹ́
ọmọ màlúù òun ọmọ kìnnìún
àti ọmọ ẹran ó wà papọ̀
ọ̀dọ́mọdé yóò sì máa dà wọ́n.
7 Màlúù àti beari yóò máa jẹun pọ̀,
àwọn ọmọ wọn yóò dùbúlẹ̀ pọ̀,
kìnnìún yóò sì máa jẹ koríko
gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù.
8 Ọ̀dọ́mọdé yóò ṣeré lẹ́bàá ihò ọká,
ọmọdé yóò ki ọwọ́ rẹ̀ bọ ìtẹ́ paramọ́lẹ̀.
9 Wọn kò ní ṣe ni léṣe tàbí pa ni run
ní gbogbo òkè mímọ́ mi,
nítorí gbogbo ayé yóò kún fún ìmọ̀ Olúwa
gẹ́gẹ́ bí omi ti bo Òkun.
10 Ní ọjọ́ náà, gbòǹgbò Jese yóò dúró gẹ́gẹ́ bí àsíá fún gbogbo ènìyàn, àwọn orílẹ̀-èdè yóò pagbo yí i ká, ibùdó ìsinmi rẹ̀ yóò jẹ́ èyí tí ó lógo. 11 Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò na ọwọ́ rẹ̀ jáde nígbà kejì láti tún gba àwọn tí ó ṣẹ́kù àní àwọn tí a ṣẹ́kù nínú àwọn ènìyàn an rẹ̀ láti Asiria wá, láti ìsàlẹ̀ Ejibiti àti òkè Ejibiti, láti Kuṣi, láti Elamu láti Babiloni, láti Hamati àti láti àwọn erékùṣù inú Òkun.
12 Òun yóò gbé àsíá sókè fún àwọn orílẹ̀-èdè,
yóò sì kó àwọn ìgbèkùn Israẹli jọ,
yóò kó gbogbo àwọn ènìyàn Juda tí a ti fọ́n káàkiri jọ,
láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé.
13 Owú jíjẹ Efraimu yóò pòórá,
àwọn ọ̀tá Juda ni a ó ké kúrò,
Efraimu kò ní jowú Juda,
tàbí Juda kó dojúkọ Efraimu.
14 Wọn yóò fò mọ́ èjìká Filistini
sí apá ìwọ̀-oòrùn,
wọn yóò pawọ́pọ̀ kọlu àwọn
ènìyàn apá ìlà-oòrùn.
Wọn yóò gbé ọwọ́ wọn lé Edomu àti Moabu,
àwọn ará Ammoni yóò sì di ìwẹ̀fà wọn.
15 Olúwa yóò sọ di gbígbé
àyasí Òkun Ejibiti,
pẹ̀lú atẹ́gùn gbígbóná ni yóò na ọwọ́ rẹ̀,
kọjá lórí odò Eufurate.
Òun yóò sì sọ ọ́ di ọmọdò méje
tó fi jẹ́ pé àwọn ènìyàn
yóò máa là á kọjá pẹ̀lú bàtà.
16 Ọ̀nà gidi yóò wà fún àwọn ènìyàn an rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù
tí ó kù sílẹ̀ ní Asiria,
gẹ́gẹ́ bí ó ti wà fún Israẹli
nígbà tí wọ́n gòkè láti Ejibiti wá.
12:1 Ní ọjọ́ náà ni ìwọ ó wí pé,
“Èmi ó yìn ọ́, Olúwa.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ò ti bínú sí mi
ìbínú rẹ ti yí kúrò níbẹ̀
ìwọ sì ti tù mí nínú.
2 Nítòótọ́ Ọlọ́run ni ìgbàlà mi,
èmi yóò gbẹ́kẹ̀lé e èmi kì yóò bẹ̀rù.
Olúwa, Olúwa náà ni agbára à mi àti orin ìn mi,
òun ti di ìgbàlà mi.”
3 Pẹ̀lú ayọ̀ ni ìwọ yóò máa pọn omi
láti inú kànga ìgbàlà.
4 Ní ọjọ́ náà, ìwọ yóò wí pé,
“Fi ọpẹ́ fún Olúwa, ké pe orúkọ rẹ̀,
jẹ́ kí ó di mí mọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,
ohun tí ó ti ṣe
kí o sì kéde pé a ti gbé
orúkọ rẹ̀ ga.
5 Kọ orin sí Olúwa, nítorí ó ti ṣe ohun tí ó lógo,
jẹ́ kí èyí di mí mọ̀ fún gbogbo ayé.
6 Kígbe sókè kí o sì kọrin fún ayọ̀, ẹ̀yin ènìyàn Sioni,
nítorí títóbi ni ẹni mímọ́ kan ṣoṣo
ti Israẹli láàrín yín.”
13:1 Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Babeli èyí tí Isaiah ọmọ Amosi rí.
2 Gbé àsíá sókè ní orí òkè gbẹrẹfu,
kígbe sí wọn,
pè wọ́n
láti wọlé sí ẹnu-ọ̀nà àwọn ọlọ́lá.
3 Mo ti pàṣẹ fún àwọn ẹni mímọ́ mi,
mo ti pe àwọn jagunjagun mi
láti gbé ìbínú mi jáde
àwọn tí ń yọ̀ nínú ìṣẹ́gun mi.
4 Gbọ́ ohùn kan ní àwọn orí òkè,
gẹ́gẹ́ bí i ti ogunlọ́gọ̀ ènìyàn.
Gbọ́ ìdàrúdàpọ̀ láàrín àwọn ìjọba,
gẹ́gẹ́ bí i ti ìkórajọ àwọn orílẹ̀-èdè!
Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti kó ogun rẹ̀ jọ
àwọn jagunjagun fún ogun.
5 Wọ́n wá láti ọ̀nà jíjìn réré,
láti ìpẹ̀kun ọ̀run wá
Olúwa pẹ̀lú àwọn ohun ìjà ìbínú rẹ̀,
láti pa gbogbo orílẹ̀-èdè náà run.
6 Ẹ hu, nítorí ọjọ́ Olúwa súnmọ́ tòsí,
yóò sì wá gẹ́gẹ́ bí ìparun láti ọ̀dọ̀ Alágbára jùlọ.
7 Nítorí èyí, gbogbo ọwọ́ ni yóò rọ,
ọkàn ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò rẹ̀wẹ̀sì.
8 Ẹ̀rù yóò gbá wọn mú,
ìrora àti ìpayínkeke yóò dìwọ́n mú,
wọn yóò kérora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó ń rọbí.
Ẹnìkínní yóò wo ẹnìkejì rẹ̀ pẹ̀lú ìpayà
ojú wọn á sì gbinájẹ.
9 Kíyèsi i, ọjọ́ Olúwa ń bọ̀
ọjọ́ búburú, pẹ̀lú ìbínú àti ìrunú gbígbóná—
láti sọ ilẹ̀ náà dahoro,
àti láti pa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ inú rẹ̀ run.
10 Àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti ìkójọpọ̀ wọn
kò sì ní fi ìmọ́lẹ̀ wọn hàn.
Àṣẹ̀ṣẹ̀yọ oòrùn yóò di òkùnkùn
àti òṣùpá kò ní fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ hàn.
11 Èmi yóò jẹ ayé ní ìyà nítorí ibi rẹ̀,
àwọn ìkà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
Èmi yóò fi òpin sí gààrù àwọn agbéraga
èmi ó sì rẹ ìgbéraga àwọn aláìláàánú sílẹ̀.
12 Èmi yóò jẹ́ kí ọkùnrin kí ó wọn
ju ojúlówó wúrà lọ,
yóò sì ṣọ̀wọ́n ju wúrà Ofiri lọ.
13 Nítorí náà èmi yóò jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó wárìrì;
ayé yóò sì mì tìtì ní ibùjókòó rẹ̀
láti ọwọ́ ìbínú Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná rẹ.
14 Gẹ́gẹ́ bí egbin tí à ń dọdẹ rẹ̀,
gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́,
ọ̀kọ̀ọ̀kan yóò padà tọ àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ,
ọ̀kọ̀ọ̀kan yóò sá padà sí ilẹ̀ abínibí i rẹ̀.
15 Ẹnikẹ́ni tí a bá gbámú ni a ó wọ́ nílẹ̀ tuurutu,
gbogbo àwọn tí ọwọ́ bá tẹ̀ ni yóò ti ipa idà kú.
16 Àwọn ọ̀dọ́mọdé wọn ni a ó fọ́ sí wẹ́wẹ́ níṣojú wọn,
gbogbo ilẹ̀ wọn ni a ó kó
àwọn aya wọn ni a ó sì bá dàpọ̀.
17 Kíyèsi i, èmi yóò ru àwọn Media sókè sí wọn,
àwọn tí kò bìkítà fún fàdákà
tí kò sì ní inú dídùn sí wúrà.
18 Ọrùn wọn yóò ré àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin lulẹ̀;
wọn kò ní ṣàánú àwọn ọ̀dọ́mọdé
tàbí kí wọn síjú àánú wo àwọn ọmọdé.
19 Babeli, ohun ọ̀ṣọ́ àwọn ìjọba
ògo ìgbéraga àwọn ará Babeli
ni Ọlọ́run yóò da ojú rẹ̀ bolẹ̀
gẹ́gẹ́ bí Sodomu àti Gomorra.
20 A kì yóò tẹ̀ ibẹ̀ dó mọ́
tàbí kí á gbé inú rẹ̀ láti ìrandíran;
ará Arabia kì yóò pa àgọ́ níbẹ̀ mọ́,
olùṣọ́-àgùntàn kan kì yóò kó ẹran rẹ̀ sinmi níbẹ̀.
21 Ṣùgbọ́n àwọn ẹranko igbó ni yóò dùbúlẹ̀ níbẹ̀,
àwọn ajáko yóò kún inú ilé wọn,
níbẹ̀ ni àwọn òwìwí yóò máa gbé
níbẹ̀ ni àwọn ewúrẹ́ igbó yóò ti máa bẹ́ kiri.
22 Ìkookò yóò máa gbó ní ibùba wọn,
àwọn ajáko nínú arẹwà ààfin wọn.