Isaiah Sọtẹ́lẹ̀ Ìparun Moabu

726 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Isaiah 15–16

1  Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Moabu,

a pa Ari run ní Moabu,

òru kan ní a pa á run!

A pa Kiri run ní Moabu,

òru kan ní a pa á run!

2 Diboni gòkè lọ sí tẹmpili rẹ̀,

sí àwọn ibi gíga rẹ̀ láti sọkún,

Moabu pohùnréré lórí Nebo àti Medeba.

Gbogbo orí ni a fá

gbogbo irùngbọ̀n ni a gé dànù.

3 Wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀ ní ojú òpópónà,

ní àwọn òrùlé àti àwọn gbàgede ìlú.

Wọ́n pohùnréré,

wọ́n dọ̀bálẹ̀ pẹ̀lú ẹkún.

4 Heṣboni àti Eleale ké sóde,

ohùn wọn ni a gbọ́ títí fi dé Jahasi.

Nítorí náà ni àwọn ọmọ-ogun Moabu ṣe kígbe

tí ọkàn wọn sì rẹ̀wẹ̀sì.

5 Ọkàn mi kígbe sókè lórí Moabu;

àwọn ìsáǹsá rẹ sálà títí dé Soari,

títí fi dé Eglati-Ṣeliṣi.

Wọ́n gòkè lọ títí dé Luhiti

wọ́n ń sọkún bí wọ́n ti ń lọ,

ní òpópónà tí ó lọ sí Horonaimu

wọ́n ń pohùnréré ìparun wọn.

6 Gbogbo omi Nimrimu ni ó ti gbẹ

àwọn koríko sì ti gbẹ,

gbogbo ewéko ti tán

ewé tútù kankan kò sí mọ́.

7 Báyìí gbogbo ọrọ̀ tí wọ́n ti ní tí wọ́n sì tò jọ

wọ́n ti kó wọn kọjá lọ lórí i gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ odò Poplari.

8 Gbohùngbohùn ń gba igbe wọn dé ìpẹ̀kun ilẹ̀ Moabu;

ìpohùnréré wọn lọ títí dé Eglaimu,

igbe ẹkún wọn ni a gbọ́ títí dé kànga Elimu.

9 Omi Dimoni kún fún ẹ̀jẹ̀,

síbẹ̀ èmi ó tún mu ohun tí ó jù báyìí lọ wá sórí Dimoni—

kìnnìún kan wá sórí àwọn ìsáǹsá Moabu

àti lórí àwọn tí ó tún ṣẹ́kù sórí ilẹ̀ náà.

16:1 Fi ọ̀dọ́-àgùntàn ṣe ẹ̀bùn

ránṣẹ́ sí aláṣẹ ilẹ̀ náà,

láti Sela, kọjá ní aginjù,

lọ sí orí òkè ọ̀dọ́mọbìnrin Sioni.

2 Gẹ́gẹ́ bí alárìnkiri ẹyẹ

tí a tì jáde kúrò nínú ìtẹ́,

bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwọn obìnrin Moabu

ní àwọn ìwọdò Arnoni.

3 “Fún wa ní ìmọ̀ràn

ṣe ìpinnu fún wa.

Jẹ́ kí òjìji rẹ dàbí òru,

ní ọ̀sán gangan.

Fi àwọn ìsáǹsá pamọ́,

má ṣe fi àwọn aṣàtìpó han.

4 Jẹ́ kí àwọn ìsáǹsá Moabu gbé pẹ̀lú rẹ,

jẹ́ ààbò fún wọn kúrò lọ́wọ́ ìparun.”

Aninilára yóò wá sí òpin,

ìparun yóò dáwọ́ dúró;

òfinràn yóò pòórá kúrò lórí ilẹ̀.

5 Nínú ìfẹ́ a ó fi ìdí ìjọba kan múlẹ̀,

ní òdodo ọkùnrin kan yóò jókòó lórí rẹ̀

ẹnìkan láti ilé Dafidi wá.

Ẹni yóò ṣe ìdájọ́, yóò sì máa wá ìdájọ́,

yóò sì máa yára wá ohun tí í ṣe òdodo.

6 Àwa ti gbọ́ nípa ìgbéraga Moabu,

ìwọ̀sí ìgbéraga rẹ̀ àti fùlenge fùlenge,

gààrù rẹ̀ àti àfojúdi rẹ̀,

ṣùgbọ́n ìfọ́nnu rẹ̀ jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.

7 Nítorí náà ni àwọn ará Moabu hu,

wọ́n jùmọ̀ hu lórí Moabu.

Sọkún kí o sì banújẹ́

fún àkàrà díndín Kiri-Hareseti.

8 Gbogbo pápá oko Heṣboni ti gbẹ,

bákan náà ni àjàrà Sibma rí.

Àwọn aláṣẹ àwọn orílẹ̀-èdè

wọ́n tẹ àwọn àyànfẹ́ àjàrà mọ́lẹ̀,

èyí tí ó ti fà dé Jaseri

ó sì ti tàn dé agbègbè aginjù.

Àwọn èhíhù rẹ̀ fọ́n jáde,

ó sì lọ títí ó fi dé Òkun.

9 Nítorí náà mo sọkún, gẹ́gẹ́ bí Jaseri ṣe sọkún,

fún àwọn àjàrà Sibma.

Ìwọ Heṣboni, ìwọ Eleale,

mo bomirin ọ́ pẹ̀lú omi ojú!

Igbe ayọ̀ lórí àwọn èso pípọ́n rẹ

àti lórí ìkórè èyí tí o ti mọ́wọ́ dúró.

10 Ayọ̀ àti ìdùnnú ni a ti mú kúrò

nínú ọgbà-igi eléso rẹ;

kò sí ẹnìkan tí ó kọrin tàbí

kígbe nínú ọgbà àjàrà:

ẹnikẹ́ni kò fún ọtí níbi ìfúntí,

nítorí mo ti fi òpin sí gbogbo igbe.

11 Ọkàn mi kérora fún Moabu gẹ́gẹ́ bí i dùùrù,

àní tọkàntọkàn mi fún ìlú Kiri-Hareseti.

12 Nígbà tí Moabu farahàn ní ibi gíga rẹ̀,

ó ṣe ara rẹ̀ ní wàhálà lásán;

nígbà tí ó lọ sí ojúbọ rẹ̀ láti gbàdúrà

òfo ni ó jásí.

13 Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa Moabu. 14 Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí Olúwa wí pé, “Láàrín ọdún mẹ́ta gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀fà tí ó wà lábẹ́ ìdè ọgbà rẹ̀ ti máa kà á, ògo Moabu àti àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn rẹ̀ ni a ó kẹ́gàn, àwọn tí ó sálà nínú rẹ̀ yóò kéré níye, wọn yóò sì jẹ́ akúrẹtẹ̀.”