Àìsàn Hesekiah

Àìsàn Hesekiah: ọ̀rọ̀ ìṣáájú.

713 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

2 Kronika 32:24–26

24  Ní ọjọ́ wọ́n nì Hesekiah ṣe àárẹ̀, ó sì dójú ikú. Ó gbàdúrà sí Olúwa tí ó dá a lóhùn, tí ó sì fún un ní àmì àgbàyanu. 25 Ṣùgbọ́n ọkàn Hesekiah ṣe ìgbéraga, kò sì kọbi ara sí i inú rere tí a fihàn án. Nítorí náà, ìbínú Olúwa wà lórí rẹ̀ àti lórí Juda àti Jerusalẹmu. 26 Nígbà náà ni Hesekiah ronúpìwàdà ní ti ìgbéraga ọkàn rẹ̀, àwọn ènìyàn Jerusalẹmu sì ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí náà, ìbínú Olúwa kò wá sí orí wọn ní ìgbà àwọn ọjọ́ Hesekiah.

2 Ọba 20:1–11

1  Ní ayé ìgbà wọ̀n-ọn-nì Hesekiah ṣe àìsàn ó sì wà ní ojú ikú. Wòlíì Isaiah ọmọ Amosi lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ: tún ilé rẹ ṣe, ṣùgbọ́n ìwọ yóò kú; o kò ní í gbádùn.”

2 Hesekiah yí ojú rẹ̀ padà sí ògiri ó sì gbàdúrà sí Olúwa pé, 3 “Rántí, Olúwa mi, bí èmi ṣe rìn níwájú rẹ àti pẹ̀lú bí èmi ṣe jẹ́ olóòtítọ́ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn ìfọkànsìn mi tí èmi sì ti ṣe ohun tí ó dára níwájú rẹ.” Hesekiah sọkún kíkorò.

4 Kí ó tó di wí pé Isaiah jáde kúrò ní àárín àgbàlá ààfin, ọ̀rọ̀ Olúwa wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé: 5 “Lọ padà kí o sì sọ fún Hesekiah, olórí àwọn ènìyàn mi pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run baba rẹ Dafidi sọ: Mo ti gbọ́ àdúrà rẹ mo sì ti rí omijé rẹ, Èmi yóò wò ọ́ sàn. Ní ọjọ́ kẹta láti ìsinsin yìí, ìwọ yóò lọ sókè ilé tí a kọ́ fún Olúwa. 6 Èmi yóò fi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kún ọjọ́ ayé rẹ. Èmi yóò sì gbà ọ́ àti ìlú ńlá yìí láti ọwọ́ ọba Asiria. Èmi yóò sì dáàbò bo ìlú yìí nítorí ti èmi tìkára mi àti nítorí ti Dafidi ìránṣẹ́ mi.’ ”

7 Nígbà náà ni Isaiah wí pé, “Mú odidi ọ̀pọ̀tọ́.” Wọ́n sì mú un, wọ́n sì fi lé oówo náà, ara rẹ̀ sì yá.

8 Hesekiah sì béèrè lọ́wọ́ Isaiah pé, “Kí ni yóò jẹ́ àmì pé Olúwa yóò wò mí sàn àti wí pé èmi yóò lọ sókè sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa láti ọjọ́ kẹta títí di òní?”

9 Isaiah dáhùn pé, “Èyí ni àmì tí Olúwa fún ọ wí pé Olúwa yóò ṣe ohun tí ó ti ṣe ìlérí: kí òjìji lọ síwájú ìgbésẹ̀ mẹ́wàá, tàbí kí ó padà lọ ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá?”

10 “Ó jẹ́ ohun ìrọ̀rùn fún òjìji láti lọ síwájú ìgbésẹ̀ mẹ́wàá,” Hesekiah wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, jẹ́ kí ó lọ padà ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá.”

11 Nígbà náà wòlíì Isaiah ké pe Olúwa, Olúwa sì ṣe òjìji padà sí ìgbésẹ̀ mẹ́wàá ó ti sọ̀kalẹ̀ ní òpópó ọ̀nà Ahasi.

Isaiah 32–33

1 Wò ó, ọba kan yóò jẹ nínú òdodo

àwọn olórí yóò máa fi ìdájọ́ ṣe àkóso.

2 Ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò jẹ́ bí ibi ìṣápamọ́ kúrò lọ́wọ́ afẹ́fẹ́

àti ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì,

gẹ́gẹ́ bí odò omi ní ilẹ̀ aṣálẹ̀,

àti bí òjìji àpáta ńlá ní ilẹ̀ gbígbẹ.

3 Nígbà náà ni ojú àwọn tí ó rí kò ní padé mọ́,

àti etí àwọn tí ó gbọ́ yóò tẹ́tí sílẹ̀.

4 Ọkàn àwọn oníwàdùwàdù ni yóò là tí yóò sì yè,

àti ahọ́n tí ń kólòlò ni yóò là geerege.

5 A kò ní pe òmùgọ̀ ní ọlọ́lá mọ́

tàbí kí a fi ọ̀wọ̀ tí ó ga jù fún aláìlóòótọ́ ènìyàn.

6 Nítorí òmùgọ̀ sọ̀rọ̀ òmùgọ̀,

ọkàn rẹ̀ kún fún ìwà ibi:

òun hùwà àìwà-bí-Ọlọ́run

ó sì ń tan àṣìṣe tí ó kan Olúwa kalẹ̀;

ẹni ebi ń pa ló fi sílẹ̀ lófo

àti fún àwọn tí òǹgbẹ ń gbẹ

ni ó mú omi kúrò.

7 Ibi ni gbogbo ọgbọ́n àwọn ìkà ènìyàn jẹ́,

ó ń gba èrò búburú

láti fi ọ̀rọ̀ èké pa tálákà run,

bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀bẹ̀ aláìní sì tọ̀nà.

8 Ṣùgbọ́n ọlọ́lá ènìyàn a máa pète ohun ńlá

àti nípa èrò rere ni yóò dúró.

9 Ẹ̀yin obìnrin tí ẹ ti gba ìtẹ́lọ́rùn gidi

ẹ dìde kí ẹ tẹ́tí sí mi,

ẹ̀yin ọ̀dọ́mọbìnrin tí ọkàn yín ti balẹ̀,

ẹ gbọ́ ohun tí mo fẹ́ sọ!

10 Ní ó lé díẹ̀ ní ọdún kan

ẹ̀yin tí ọkàn an yín balẹ̀ yóò wárìrì;

ìkórè àjàrà kò ní múnádóko,

bẹ́ẹ̀ ni ìkórè èso kò ní sí.

11 Wárìrì, ẹ̀yin obìnrin onítẹ̀lọ́rùn;

bẹ̀rù, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọbìnrin tí ẹ rò pé ọkàn yín balẹ̀!

Ẹ bọ́ aṣọ yín kúrò,

ẹ ró aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́ yín.

12 Ẹ lu ọmú yín fún pápá ìgbádùn náà,

fún àwọn àjàrà eléso

13 àti fún ilẹ̀ àwọn ènìyàn mi,

ilẹ̀ tí ó ti kún fún ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n,

bẹ́ẹ̀ ni, kẹ́dùn fún gbogbo ilé ìtura

àti fún ìlú àríyá yìí.

14 Ilé olódi ni a ó kọ̀sílẹ̀,

ìlù aláriwo ni a ó kọ̀ tì;

ilé olódi àti ilé ìṣọ́ ni yóò di ihò títí láéláé,

ìdùnnú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti pápá

oko fún àwọn ẹran ọ̀sìn,

15 títí a ó fi tú Ẹ̀mí sí wa lórí láti òkè wá,

àti ti aṣálẹ̀ tí yóò dí pápá oko ọlọ́ràá

àti tí pápá ọlọ́ràá yóò dàbí ẹgàn.

16 Ẹ̀tọ́ yóò máa gbé ní inú aṣálẹ̀

àti òdodo yóò sì máa gbé ní pápá oko ọlọ́ràá.

17 Èso òdodo náà yóò sì jẹ́ àlàáfíà;

àbájáde òdodo yóò sì jẹ́ ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé títí láé.

18 Àwọn ènìyàn mi yóò máa gbé ní ibùgbé àlàáfíà,

ní ibùgbé ìdánilójú,

ní àwọn ibi ìsinmi tí ó parọ́rọ́.

19 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé yìnyín ti tẹ́jú igbó pẹrẹsẹ

àti tí ojú ìlú ti tẹ́ pẹrẹsẹ pátápátá,

20 báwo ni ẹ ó ti jẹ́ alábùkún tó,

nípa gbígbin irúgbìn sí ipa odò gbogbo,

àti nípa jíjẹ́ kí àwọn màlúù yín àti

àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ jẹ láìsí ìdíwọ́.

33:1 Ègbé ni fún ọ, ìwọ apanirun,

ìwọ tí a kò tí ì parun!

Ègbé ni fún ọ, ìwọ ọ̀dàlẹ̀,

ìwọ tí a kò tí ì dà ọ́!

Nígbà tí o bá dẹ́kun à ń pa ni run;

a ó pa ìwọ náà run,

nígbà tí o bá dẹ́kun à ń dani,

a ó da ìwọ náà.

2 Olúwa ṣàánú fún wa

àwa ń ṣàfẹ́rí i rẹ.

Máa jẹ́ agbára wa ní òròòwúrọ̀

ìgbàlà wa ní àsìkò ìpọ́njú.

3 Ní ìkérara ohùn rẹ, àwọn ènìyàn sá,

nígbà tí o dìde sókè, àwọn orílẹ̀-èdè fọ́nká.

4 Ìkógun rẹ, ìwọ orílẹ̀-èdè ni a kórè

gẹ́gẹ́ bí i ti ọ̀dọ́ eṣú;

gẹ́gẹ́ bí àkójọpọ̀ eṣú, àwọn ènìyàn wọ ibẹ̀.

5 A gbé Olúwa ga, nítorí pé ó ń gbé ibi gíga,

Òun yóò kún Sioni pẹ̀lú ẹ̀tọ́ àti òdodo.

6 Òun yóò jẹ́ ìpìlẹ̀ tí ó dájú fún àkókò rẹ

ibùjókòó ìgbàlà kíkún àti ọgbọ́n òun ìmọ̀;

ìbẹ̀rù Olúwa ni kọ́kọ́rọ́ sí ìṣúra yìí.

7 Wò ó, àwọn onígboyà ọkùnrin wọn pohùnréré

ẹkún ní òpópónà;

àwọn ikọ̀ àlàáfíà sọkún kíkorò.

8 Àwọn ojú ọ̀nà ńlá ni a ṣá tì,

kò sí arìnrìn-àjò kankan ní ojú ọ̀nà.

A ti ba àdéhùn jẹ́,

a kẹ́gàn àwọn ẹlẹ́rìí,

a kò bu ọlá fún ẹnikẹ́ni.

9 Ilẹ̀ ṣọ̀fọ̀ ó sì ṣòfò dànù,

ojú ti Lebanoni ó sì sá

Ṣaroni sì dàbí aginjù,

àti Baṣani òun Karmeli rẹ àwọn èwe wọn.

10 “Ní ìsinsin yìí ni èmi yóò dìde,” ni Olúwa wí.

“Ní ìsinsin yìí ni a ó gbé mi ga,

ní ìsinsin yìí ni a ó gbé mi sókè.

11 Ìwọ lóyún ìyàngbò,

o sì bí koríko;

èémí yín bí iná tí yóò jẹ yín run.

12 A ó jó àwọn ènìyàn run bí eérú;

bí igbó ẹ̀gún tí a gé la ó dáná sí wọn.”

13 Ìwọ tí ó wà lọ́nà jíjìn, gbọ́ ohun tí mo ti ṣe;

ìwọ tí ò ń bẹ nítòsí, jẹ́rìí agbára mi!

14 Ẹ̀rù ba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní Sioni;

ìwárìrì bá àwọn tí kò gba Ọlọ́run gbọ́:

“Ta ni nínú wa lólè gbé pẹ̀lú iná ajónirun?

Ta ni nínú wa lólè gbé pẹ̀lú iná àìnípẹ̀kun?”

15 Ẹni tí ó ń rìn lódodo

tí ó ń sọ ohun tí ó tọ́,

tí ó kọ èrè tí ó ti ibi ìlọ́nilọ́wọ́gbà wá,

tí ó sì pa ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò nínú gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀,

tí ó di etí rẹ̀ sí ọ̀tẹ̀ láti pànìyàn

tí ó sì di ojú rẹ̀ sí à ti pète ibi,

16 Òun náà yóò gbé ní ibi gíga,

ibi ààbò rẹ̀ yóò jẹ́ òkè ńlá olódi.

A ó mú oúnjẹ fún un,

omi rẹ̀ yóò sì dájú.

17 Ojú rẹ yóò rí ọba nínú ẹwà rẹ̀

yóò sì rí ilẹ̀ kan tí ó tẹ́ lọ rẹrẹẹrẹ.

18 Nínú èrò rẹ ìwọ yóò rántí ẹ̀rù rẹ àtẹ̀yìnwá:

“Níbo ni ọ̀gá àgbà náà wà?

Níbo ni ẹni tí ń gba owó òde wà?

Níbo ni òṣìṣẹ́ ti ó ń mójútó ilé ìṣọ́ wà?”

19 Ìwọ kì yóò rí àwọn agbéraga ènìyàn mọ́,

àwọn ènìyàn tí èdè wọn fi ara sin,

pẹ̀lú ahọ́n tí ó ṣàjèjì tí kò sì yé ni.

20 Gbójú sókè sí Sioni, ìlú àjọ̀dún wa,

ojú rẹ yóò rí Jerusalẹmu,

ibùgbé àlàáfíà n nì, àgọ́ tí a kò ní yí padà;

àwọn òpó rẹ̀ ni a kì yóò fàtu

tàbí èyíkéyìí nínú okùn rẹ̀ kí já.

21 Níbẹ̀ ni Olúwa yóò ti jẹ́ alágbára kan fún wa.

Yóò sì dàbí ibi àwọn odò ńlá ńlá àti odò kéékèèké.

Kì yóò sí ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú tí yóò kọjá lórí i wọn,

ọkọ̀ ojú omi ńlá ni a kì yóò tù lórí wọn.

22 Nítorí Olúwa ni onídàájọ́ wa,

Olúwa ni onídàájọ́ wa,

Olúwa òun ni ọba wa;

òun ni ẹni tí yóò gbà wá là.

23 Gbogbo okùn rẹ ni ó ti dẹ̀:

Ìgbókùnró kò fìdímúlẹ̀,

wọn kò taṣọ agbọ́kọ̀rìn,

lẹ́yìn náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkógun ni a ó pín

àní arọ pẹ̀lú yóò ru ìkógun lọ.

24 Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó ń gbé Sioni tí yóò wí pé, “Ara mi kò yá,”

a ó dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn tí ń gbé ibẹ̀ jì wọ́n.