Elihu Sọ Pé Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ni Ìpọ́njú Ti Wá (continued)

Elihu, tí ó ti dákẹ́ títí di ìsinsìnyí, bẹ̀rẹ̀ sí í dá sí àríyànjiyàn náà. Ó fi hàn pé Ọlọ́run ń rán ìpọ́njú fún àwọn ète ọlọ́gbọ́n, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò lè ṣàwárí wọn, àti pé ojúṣe ènìyàn ni láti tẹríba.

2130 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Jobu 36–37

1 Elihu sì tún sọ̀rọ̀ wí pé,

2 “Fún mi láyè díẹ̀ èmi ó sì fihàn ọ́,

nítorí ọ̀rọ̀ sísọ ní ó kún fún Ọlọ́run.

3 Èmi ó mú ìmọ̀ mi ti ọ̀nà jíjìn wá,

èmi ó sì fi òdodo fún Ẹlẹ́dàá mi.

4 Rí i dájú pé ọ̀rọ̀ mi kì yóò ṣèké nítòótọ́;

ẹni tí ó pé ní ìmọ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀.

5 “Kíyèsi i, Ọlọ́run ni alágbára, òun kò i sì gàn ènìyàn;

ó ní agbára ní ipá àti òye.

6 Òun kì í dá ẹ̀mí ènìyàn búburú sí,

ṣùgbọ́n ó fi òtítọ́ fún àwọn tálákà.

7 Òun kì í mú ojú rẹ̀ kúrò lára olódodo,

ṣùgbọ́n àwọn ọba ni wọ́n wà lórí ìtẹ́;

àní ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láéláé, a sì gbé wọn lékè.

8 Bí ó bá sì dè wọ́n nínú àbà,

tí a sì fi okùn ìpọ́njú dè wọ́n,

9 nígbà náà ni ó ń sọ àwọn ohun tí wọn ti ṣe fún wọn,

wí pé wọ́n ti ṣẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga wọn.

10 Ó sí wọn létí pẹ̀lú sí ọ̀nà ẹ̀kọ́,

ó sì pàṣẹ kí wọn kí ó padà kúrò nínú àìṣedédé.

11 Bí wọ́n bá gbàgbọ́ tí wọ́n sì sìn ín,

wọn ó lo ọjọ́ wọn ní ìrọ̀rùn,

àti ọdún wọn nínú afẹ́.

12 Ṣùgbọ́n, bí wọn kò bá gbàgbọ́,

wọ́n ó ti ọwọ́ idà ṣègbé,

wọ́n á sì kú láìní òye.

13 “Ṣùgbọ́n àwọn àgàbàgebè ní ayé kó ìbínú jọ;

wọn kò kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nígbà tí ó bá wọ́n wí.

14 Nígbà náà ni ọkàn wọn yóò kú ní èwe,

ní àárín àwọn ọkùnrin alágbèrè ojúbọ òrìṣà.

15 Òun gba òtòṣì nínú ìpọ́njú wọn,

a sì sọ̀rọ̀ sí wọn ní etí nínú ìnira wọn.

16 “Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lúpẹ̀lú ó fa wọn yọ láti inú ìhágágá sí ibi gbòòrò,

sí ibi tí ó ní ààyè tí kò ní wàhálà nínú rẹ̀,

ohun tí a sì gbé kalẹ̀ ní tábìlì rẹ̀ jẹ́ kìkì ọ̀rá oúnjẹ tí ó fẹ́.

17 Ṣùgbọ́n ìwọ kún fún ìdájọ́ àwọn búburú;

ìdájọ́ àti òtítọ́ dì ọ́ mú.

18 Nítorí ìbínú ń bẹ, ṣọ́ra kí òtítọ́ rẹ máa bá a tàn ọ;

láti jẹ́ kí títóbi rẹ mú ọ ṣìnà.

19 Ọrọ̀ rẹ pọ̀ tó, tí wàhálà kì yóò fi dé bá ọ bí?

Tàbí ipa agbára rẹ?

20 Má ṣe ìfẹ́ òru, nígbà tí a ń ké

àwọn orílẹ̀-èdè kúrò ní ipò wọn.

21 Máa ṣọ́ra kí ìwọ ki ó má yí ara rẹ̀ padà sí búburú,

nítorí èyí tí ìwọ rò pé ó dára jù ìpọ́njú lọ.

22 “Kíyèsi i, Ọlọ́run ni gbéga nípa agbára rẹ̀;

ta ni jẹ́ olùkọ́ni bí rẹ̀?

23 Ta ni ó là ọ̀nà iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ fún un,

tàbí ta ni ó lè wí pé ìwọ ti ń ṣe àìṣedéédéé?

24 Rántí kí ìwọ kí ó gbé iṣẹ́ rẹ̀ ga,

ti ènìyàn ni yín nínú orin.

25 Olúkúlùkù ènìyàn a máa rí i;

ẹni ikú a máa wò ó ní òkèrè.

26 Kíyèsi i, Ọlọ́run tóbi, àwa kò sì mọ̀ bí ó ti ní òye tó,

bẹ́ẹ̀ ni a kò lè wádìí iye ọdún rẹ̀ rí.

27 “Nítorí pé òun ni ó fa ìkán omi òjò sílẹ̀,

kí wọn kí ó kán bí òjò ní ìkùùkuu rẹ̀,

28 tí àwọsánmọ̀ ń rọ̀ ìrì rẹ̀ sílẹ̀,

tí ó sì fi ń sẹ̀ lọ́pọ̀lọ́pọ̀ lórí ènìyàn.

29 Pẹ̀lúpẹ̀lú ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni lè ní ìmọ̀ ìtànká àwọsánmọ̀,

tàbí ariwo àrá láti àgọ́ rẹ̀?

30 Kíyèsi i, ó tan ìmọ́lẹ̀ yí ara rẹ̀ ká

ó sì bo ìsàlẹ̀ òkun mọ́lẹ̀.

31 Nítorí pé nípa wọn ní ń ṣe dájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ènìyàn;

ó sí ń pèsè oúnjẹ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.

32 Ó fi ìmọ́lẹ̀ bo ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì

ó sì rán an sí ẹni olódì.

33 Ariwo àrá rẹ̀ fi ìjì hàn ní;

ọ̀wọ́ ẹran pẹ̀lú wí pé, ó súnmọ́ etílé!

37:1 “Àyà sì fò mi sí èyí pẹ̀lú,

ó sì kúrò ní ipò rẹ̀.

2 Fetísílẹ̀! Fetísílẹ̀, kí ẹ sì gbọ́ ìró ohùn rẹ̀,

àti èyí tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde wá.

3 Ó ṣe ìlànà rẹ̀ ní ìsàlẹ̀ ọ̀run gbogbo,

mọ̀nàmọ́ná rẹ̀ ni ó sì jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ dé òpin ilẹ̀ ayé.

4 Lẹ́yìn mọ̀nàmọ́ná ohùn kan fọ̀ ramúramù;

ó sì fi ohùn ọláńlá rẹ̀ sán àrá.

Òhun kì yóò sì dá àrá dúró,

nígbà tí ó bá ń gbọ́ ohùn rẹ̀.

5 Ọlọ́run fi ohùn rẹ̀ sán àrá ní ọ̀nà ìyanu;

ohùn ńlá ńlá ni í ṣe tí àwa kò le mọ̀.

6 Nítorí tí ó wí fún yìnyín pé, ‘Ìwọ rọ̀ sílẹ̀ ayé,’

àti pẹ̀lú fún ọwọ́ òjò, ‘Fún òjò ńlá agbára rẹ̀.’

7 Ó fi èdìdì di ọwọ́ gbogbo ènìyàn kí gbogbo wọn kí ó lè mọ iṣẹ́ rẹ̀,

ó sì tún dá olúkúlùkù ènìyàn dúró lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀.

8 Nígbà náà ní àwọn ẹranko wọ inú ihò lọ,

wọn a sì wà ni ipò wọn.

9 Láti ìhà gúúsù ni ìjì àjàyíká tí jáde wá,

àti òtútù láti inú afẹ́fẹ́ ti tú àwọsánmọ̀ ká.

10 Nípa ẹ̀mí Ọlọ́run a fi ìdí omi fún ni,

ibú omi á sì súnkì.

11 Pẹ̀lúpẹ̀lú ó fi omi púpọ̀ mú àwọsánmọ̀ wúwo,

a sì tú àwọsánmọ̀ ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ká ara wọn.

12 Àwọn wọ̀nyí yí káàkiri nípa ìlànà rẹ̀,

kí wọn kí ó lè ṣe ohunkóhun

tí ó pàṣẹ fún wọn lórí ilẹ̀ ayé.

13 Ó mú àwọsánmọ̀ wá, ìbá ṣe fún ìkìlọ̀,

tàbí omi wá sí ayé láti fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn.

14 “Jobu, dẹtí sílẹ̀ sí èyí;

dúró jẹ́ẹ́ kí o sì ro iṣẹ́ ìyanu Ọlọ́run.

15 Ṣe ìwọ mọ àkókò ìgbà tí Ọlọ́run ṣe wọ́n lọ́jọ̀,

tí ó sì mú ìmọ́lẹ̀ àwọsánmọ̀ rẹ̀ dán?

16 Ṣé ìwọ mọ ìgbà tí àwọsánmọ̀ í fò lọ,

iṣẹ́ ìyanu ẹni tí ó pé ní ìmọ̀?

17 Ìwọ ẹni ti aṣọ rẹ̀ ti máa n gbóná,

nígbà tí ó fi atẹ́gùn ìhà gúúsù mú ayé dákẹ́.

18 Ìwọ ha ba tẹ́ pẹpẹ ojú ọ̀run, tí ó dúró ṣinṣin,

tí ó sì dàbí dígí tí ó yọ̀ dà?

19 “Kọ́ wa ní èyí tí a lè wí fún un;

nítorí pé àwa kò le wádìí ọ̀rọ̀ náà nítorí òkùnkùn wa.

20 A ó ha wí fún un pé, èmi fẹ́ sọ̀rọ̀?

Tàbí ẹnìkan lè wí pé, ìfẹ́ mi ni pé kí a gbé mi mì?

21 Síbẹ̀ nísinsin yìí ènìyàn kò rí

oòrùn tí ń dán nínú àwọsánmọ̀,

ṣùgbọ́n afẹ́fẹ́ ń kọjá, a sì gbá wọn mọ́.

22 Wúrà dídán ti inú ìhà àríwá jáde wá;

lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni ọláńlá ẹ̀rù ńlá wa.

23 Nípa ti Olódùmarè àwa kò le wádìí rẹ̀, ó rékọjá ní ipá;

nínú ìdájọ́ àti títí bi òun kì í ba ẹ̀tọ́ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ òtítọ́ jẹ́.

24 Nítorí náà ènìyàn ha máa bẹ̀rù rẹ̀,

òun kì í ṣe ojú sájú ẹnikẹ́ni tí ó gbọ́n ní ayé?”