Panṣágà Dafidi (continued)

1035 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Saamu 32–33

Ti Dafidi. Maskili.

1  Ìbùkún ni fún àwọn

tí a dárí ìrékọjá wọn jì,

tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀.

2 Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà

ẹni tí Olúwa kò ka ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ sí i lọ́rùn

àti nínú ẹ̀mí ẹni tí kò sí ẹ̀tàn.

3 Nígbà tí mo dákẹ́,

egungun mi di gbígbó dànù

nípa ìkérora mi ní gbogbo ọjọ́.

4 Nítorí pé ni ọ̀sán àti ní òru

ọwọ́ rẹ̀ wúwo sí mi lára;

agbára mi gbẹ tán

gẹ́gẹ́ bí ooru ẹ̀ẹ̀rùn. Sela.

5 Èmi jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ọ

àti pé èmi kò sì fi àìṣòdodo mi pamọ́.

Èmi wí pé, “Èmi yóò jẹ́wọ́

ẹ̀ṣẹ̀ mi fún Olúwa,”

ìwọ sì dárí

ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí. Sela.

6 Nítorí náà jẹ́ kí gbogbo àwọn olódodo máa gbà àdúrà sí ọ

ní ìgbà tí a lè rí ọ;

nítòótọ́ nígbà tí ìṣàn omi ńlá bá ru sókè,

wọn kì yóò lè dé ọ̀dọ̀ rẹ̀.

7 Ìwọ ni ibi ìpamọ́ mi;

ìwọ yóò pa mí mọ́ kúrò nínú ìyọnu;

ìwọ yóò fi orin ìgbàlà yí mi ka. Sela.

8 Èmi yóò kọ́ ọ, èmi yóò sì fi ẹsẹ̀ rẹ lé ọ̀nà tí ìwọ yóò rìn

èmi yóò máa gbà ọ́ ní ìyànjú, èmi yóò sì máa fi ojú mi tọ́ ọ.

9 Má ṣe dàbí ẹṣin tàbí ìbáaka,

tí kò ní òye

ẹnu ẹni tí a gbọdọ̀ fi ìjánu bọ̀,

kí wọn má ba à súnmọ́ ọ.

10 Ọ̀pọ̀ ìkáàánú ní yóò wà fún ènìyàn búburú,

ṣùgbọ́n ìfẹ́ Olúwa tí ó dúró ṣinṣin

ni yóò yí àwọn tí ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa ká.

11 Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, kí ẹ sì ní inú dídùn, ẹ̀yìn olódodo;

ẹ sì máa kọrin, gbogbo ẹ̀yìn tí àyà yín dúró ṣinṣin.

33:1 Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, ẹ̀yin olódodo;

ìyìn si yẹ fún ẹni dídúró ṣinṣin.

2 Ẹ yin Olúwa pẹ̀lú dùùrù;

ẹ máa fi ohun èlò olókùn mẹ́wàá kọrin sí i.

3 Ẹ kọ orin tuntun sí i;

ẹ máa fi ọgbọọgbọ́n lu ohun èlò orin sí i, pẹ̀lú ariwo.

4 Nítorí pé ọ̀rọ̀ Olúwa dúró ṣinṣin,

gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ ni à ń ṣe nínú òtítọ́.

5 Ó fẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́;

ilé ayé kún fún ìdúró ṣinṣin àti àánú Olúwa.

6 Nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa ni a ṣe dá àwọn ọ̀run,

àti gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ogun wọn nípa ìmísí ẹnu rẹ̀.

7 Ó kó àwọn omi òkun jọ gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó wà nínú ìgò;

ó sì fi ibú ṣe ilé ìṣúra gbogbo.

8 Jẹ́ kí gbogbo ayé kí ó bẹ̀rù Olúwa:

jẹ́ kí gbogbo àwọn olùgbé ayé kí ó wà nínú ìbẹ̀rù rẹ̀.

9 Nítorí tí ó sọ̀rọ̀, ó sì ti rí bẹ́ẹ̀;

ó pàṣẹ ó sì dúró ṣinṣin.

10 Olúwa ti mú ìmọ̀ràn àwọn orílẹ̀-èdè wá sí asán;

ó sì mú àrékérekè àwọn ènìyàn di ṣíṣákì í.

11 Ìgbìmọ̀ Olúwa dúró títí ayérayé,

àní ìrò inú rẹ̀ láti ìrandíran ni.

12 Ìbùkún ni fún orílẹ̀-èdè náà, Ọlọ́run ẹni tí Olúwa jẹ́ tirẹ̀,

àti àwọn ènìyàn náà tí ó ti yàn ṣe ìní rẹ̀.

13 Olúwa wò láti ọ̀run wá;

Ó sì rí gbogbo ìran ènìyàn.

14 Níbi tí ó ti jókòó lórí ìtẹ́

Ó wo gbogbo àwọn olùgbé ayé

15 ẹni tí ó ṣe àyà wọn bákan náà,

ó sì kíyèsi ìṣe wọn.

16 A kò gba ọba kan là nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ-ogun;

kò sì sí jagunjagun tí a gbà sílẹ̀ nípa agbára ńlá rẹ̀.

17 Ohun asán ni ẹṣin fún ìṣẹ́gun;

bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi agbára ńlá rẹ̀ gbani sílẹ̀.

18 Wò ó, ojú Olúwa wà lára àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,

àti lára àwọn tí ó ní ìrètí nínú ìfẹ́ rẹ̀ tí ó dúró ṣinṣin.

19 Láti gba ọkàn wọn kúrò lọ́wọ́ ikú

àti láti pa wọ́n mọ́ láààyè lọ́wọ́ ìyàn.

20 Ọkàn wa dúró de Olúwa;

òun ni ìrànlọ́wọ́ wa àti asà wa.

21 Ọkàn wa yọ̀ nínú rẹ̀,

nítorí pé, àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ rẹ mímọ́.

22 Kí àánú rẹ, Olúwa, kí ó wà lára wa,

àní gẹ́gẹ́ bí àwa ti ń ṣe ìrètí nínú rẹ.