Dafidi títí di ìgbà tí ó sá kúrò ní ààfin Saulu (continued)

1063 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

1 Samuẹli 19:1–3

1 Saulu sọ fún Jonatani ọmọ rẹ̀ àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n pa Dafidi. Ṣùgbọ́n Jonatani fẹ́ràn Dafidi púpọ̀ 2 Jonatani sì kìlọ̀ fún Dafidi pé, “Baba mi Saulu wá ọ̀nà láti pa ọ́, kíyèsi ara rẹ di òwúrọ̀ ọ̀la; lọ sí ibi ìkọ̀kọ̀, kí o sì sá pamọ́ sí ibẹ̀. 3 Èmi yóò jáde lọ láti dúró ní ọ̀dọ̀ baba mi ní orí pápá níbi tí ó wà. Èmi yóò sọ̀rọ̀ fún un nípa à rẹ, èmi yóò sì sọ ohun tí òun bá wí fún ọ.”

Saamu 11

Fún adarí orin. Ti Dafidi.

1 Ìgbẹ́kẹ̀lé mi wà nínú Olúwa.

Báwo ní ẹ̀yin ó ṣe sọ fún ọkàn mi pé,

“Fò gẹ́gẹ́ bi ẹyẹ lọ si orí òkè rẹ.

2 Wò ó nítorí náà, ènìyàn búburú fa ọfà rẹ̀;

wọn ti fi ọfà wọn sí ojú okùn

láti tafà níbi òjìji

sí àyà ẹni ìdúró ṣinṣin.

3 Nígbà tí ìpìlẹ̀ bá bàjẹ́

kí ni olódodo yóò ṣe?”

4 Olúwa ń bẹ nínú tẹmpili mímọ́ rẹ̀;

Olúwa ń bẹ lórí ìtẹ́ rẹ̀ ní ọ̀run.

Ó ń wo àwọn ọmọ ènìyàn;

ojú rẹ̀ ń yẹ̀ wọ́n wò.

5 Olúwa ń yẹ olódodo wò,

ṣùgbọ́n ènìyàn búburú àti àwọn tí o fẹ́ ìwà ipá

ni ọkàn rẹ̀ kórìíra.

6 Sí orí àwọn ènìyàn búburú ni yóò rọ̀jò

ẹ̀yín iná àti imí-ọjọ́ tí ń jó;

àti ìjì gbígbóná ní yóò jẹ ìpín wọn.

7 Nítorí, olódodo ní Olúwa,

o fẹ́ràn òdodo;

ẹni ìdúró ṣinṣin yóò sì rí i.

1 Samuẹli 19:4–17

4 Jonatani sọ̀rọ̀ rere nípa Dafidi fún Saulu baba rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Má ṣe jẹ́ kí ọba kí ó ṣe ohun tí kò dára fún Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀; nítorí tí kò ṣẹ̀ ọ́, ohun tí ó sì ṣe pé ọ púpọ̀. 5 Ó fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu nígbà tí ó pa Filistini. Olúwa ṣẹ́ ogun ńlá fún gbogbo Israẹli, ìwọ rí i inú rẹ dùn. Ǹjẹ́ nítorí kí ni ìwọ yóò ṣe dẹ́ṣẹ̀ sí Dafidi aláìṣẹ̀, tí ìwọ yóò fi pa á láìnídìí?”

6 Saulu fetísí Jonatani, ó sì búra báyìí, “Níwọ́n ìgbà tí Olúwa bá ti ń bẹ láààyè, a kì yóò pa Dafidi.”

7 Nítorí náà Jonatani pe Dafidi, ó sì sọ gbogbo àjọsọ wọn fún un. Ó sì mú un wá fún Saulu, Dafidi sì wà lọ́dọ̀ Saulu gẹ́gẹ́ bí i ti tẹ́lẹ̀.

8 Lẹ́ẹ̀kan an sí i ogun tún wá, Dafidi sì jáde lọ, ó sì bá àwọn ara Filistini jà. Ó sì pa wọn pẹ̀lú agbára, wọ́n sì sálọ níwájú u rẹ̀.

9 Ṣùgbọ́n ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá sí orí Saulu bí ó ti jókòó ní ilé e rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀. Bí Dafidi sì ti fọn ohun èlò orin olókùn, 10 Saulu sì wá ọ̀nà láti gún un mọ́ ògiri pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n Dafidi yẹ̀ ẹ́ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Saulu ti ju ọ̀kọ̀ náà mọ́ ara ògiri. Ní alẹ́ ọjọ́ náà Dafidi sì fi ara pamọ́ dáradára.

11 Saulu rán ènìyàn sí ilé Dafidi láti ṣọ́ ọ kí wọ́n sì pa á ní òwúrọ̀. Ṣùgbọ́n Mikali, ìyàwó Dafidi kìlọ̀ fún un pé, “Tí o kò bá sá fún ẹ̀mí rẹ ní alẹ́ yìí, ní ọ̀la ni a yóò pa ọ́.” 12 Nígbà náà Mikali sì gbé Dafidi sọ̀kalẹ̀ ó sì fi aṣọ bò ó. 13 Mikali gbé ère ó sì tẹ́ e lórí ibùsùn, ó sì fi irun ewúrẹ́ sí ibi orí rẹ̀.

14 Nígbà ti Saulu rán ènìyàn láti lọ fi agbára mú Dafidi, Mikali wí pé, “Ó rẹ̀ ẹ́.”

15 Nígbà náà ni Saulu rán ọkùnrin náà padà láti lọ wo Dafidi ó sì sọ fún wọn pé, “Mú wa fún mi láti orí ibùsùn rẹ̀ kí èmi kí ó le pa á.” 16 Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkùnrin náà wọlé, ère ni ó bá lórí ibùsùn àti irun ewúrẹ́ ní orí ère náà.

17 Saulu wí fún Mikali pé, “Èéṣe tí ìwọ fi tàn mí báyìí tí o sì jẹ́ kí ọ̀tá mi sálọ tí ó sì bọ́?”

Mikali sọ fún un pé, “Ó wí fún mi, ‘Jẹ́ kí èmi ó lọ. Èéṣe tí èmi yóò fi pa ọ́?’ ”

Saamu 59

Fún adarí orin. Tí ohùn orin “Má ṣe parun.” Ti Dafidi. Miktamu. Nígbà tí Saulu rán àwọn olùṣọ́ sí ilé Dafidi kí òun bá le rí i pa.

1 Gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá à mi, Ọlọ́run;

dáàbò bò mí kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ó dìde sí mi.

2 Gbà mí lọ́wọ́ àwọn oníṣẹ́ búburú

kí o sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ènìyàn tí ń pòǹgbẹ ẹ̀jẹ̀.

3 Wò ó, bí wọ́n ṣe ba ní bùba dè mí!

Àwọn alágbára ń gbìmọ̀ lòdì sí mi

kì í ṣe nítorí ìrékọjá mi tàbí ẹ̀ṣẹ̀ mí, Olúwa.

4 Èmi kò ṣe àìṣedéédéé kan, síbẹ̀ wọ́n sáré wọ́n ṣetán láti kọlù mí.

Dìde fún ìrànlọ́wọ́ mi, kí o sì wo àìlera mi.

5 Olúwa Ọlọ́run Alágbára,

Ọlọ́run Israẹli,

dìde fún ara rẹ kí o sì bá àwọn orílẹ̀-èdè wí;

má ṣe ṣàánú fún àwọn olùrékọjá búburú nì. Sela.

6 Wọ́n padà ní àṣálẹ́,

wọ́n ń gbó bí àwọn ajá,

wọ́n ń rìn yí ìlú náà káàkiri.

7 Kíyèsi ohun tí wọ́n tú jáde ní ẹnu:

wọn ń tú idà jáde láti ètè wọn,

wọ́n sì wí pé, “Ta ni ó lè gbọ́ ọ̀rọ̀ wa?”

8 Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, yóò fi wọ́n rẹ́rìn-ín,

Ìwọ ó yọ ṣùtì sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.

9 Ìwọ agbára mi, èmi ó máa kọrin ìyìn sí ọ;

nítorí ìwọ Ọlọ́run ni ààbò mi,

10 Ọlọ́run àánú mi ni yóò ṣáájú mi.

Ọlọ́run yóò sì jẹ́ kí èmi rí ìfẹ́ mi lára àwọn ọ̀tá mi.

Yóò sì jẹ́ kí n yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí ìfẹ́ àwọn ọ̀tá mi.

11 Ṣùgbọ́n má ṣe pa wọ́n, Olúwa asà wa,

kí àwọn ènìyàn mi má ba à gbàgbé.

Nínú agbára rẹ, jẹ́ kí wọn máa rìn kiri,

kí o sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀.

12 Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ẹnu wọn,

ní ọ̀rọ̀ ètè wọn,

kí a mú wọn nínú ìgbéraga wọn.

Nítorí èébú àti èké tí wọn ń sọ,

13 pa wọ́n run nínú ìbínú,

run wọ́n di ìgbà tí wọn kò ní sí mọ́.

Nígbà náà ni yóò di mí mọ̀ dé òpin ayé

pé Ọlọ́run jẹ ọba lórí Jakọbu. Sela.

14 Wọ́n padà ní àṣálẹ́,

wọn ń gbó bí àwọn ajá

wọ́n ń rin ìlú náà káàkiri.

15 Wọ́n ń rin kiri fún oúnjẹ

wọ́n sì ń yán nígbà tí wọn kò yó.

16 Ṣùgbọ́n èmi ó kọrin agbára rẹ,

n ó kọrin ìfẹ́ rẹ ní òwúrọ̀;

nítorí ìwọ ni ààbò mi,

ibi ìsádi mi ní ìgbà ìpọ́njú.

17 Ìwọ agbára mi, èmi ó kọrin ìyìn sí ọ;

ìwọ, Ọlọ́run, ààbò mi, Ọlọ́run ìfẹ́ mi.