A kọ̀ fún Dafidi láti kọ́ tẹmpili (continued)

1044 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Saamu 16

Miktamu ti Dafidi.

1 Pa mí mọ́, Ọlọ́run,

nítorí nínú rẹ ni ààbò mi wà.

2 Mo sọ fún Olúwa, “Ìwọ ni Olúwa mi,

lẹ́yìn rẹ èmi kò ní ìre kan.”

3 Sí àwọn ènìyàn tí ó wà ní ayé,

àwọn ni ológo nínú èyí tí ayọ̀ mí wà.

4 Ìṣòro àwọn wọ̀n-ọn-nì yóò pọ̀ sí i, àní àwọn tí ń tọ ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn.

Ẹbọ ohun mímu ẹ̀jẹ̀ wọn ni èmi kì yóò ta sílẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò dá orúkọ wọn lẹ́nu mi.

5 Olúwa, ni ìpín ìní mi tí mo yàn àti ago mi,

ó ti pa ohun tí í ṣe tèmi mọ́.

6 Okùn ààlà ilẹ̀ ti bọ́ sí ọ̀dọ̀ mi ní ibi dídára;

nítòótọ́ mo ti ní ogún rere.

7 Èmi yóò yin Olúwa, ẹni tí ó gbà mí ní ìyànjú;

ní òru, ọkàn mí ń bá mi sọ̀rọ̀.

8  Mo ti gbé Olúwa síwájú mi ní ìgbà gbogbo.

Nítorí tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, a kì yóò mì mí.

9 Nítorí èyí, ọkàn mi yọ̀, ahọ́n mi pẹ̀lú ń fò fáyọ̀;

ara mi pẹ̀lú yóò sinmi ní ààbò,

10  nítorí ìwọ kò ní fi ọ̀kan sílẹ̀ nínú isà òkú,

tàbí kí ìwọ jẹ́ kí ẹni mímọ́ rẹ kí ó rí ìdíbàjẹ́.

11 Ìwọ ti fi ipa ọ̀nà ìyè hàn mí;

Ìwọ yóò kún mi pẹ̀lú ayọ̀ ní iwájú rẹ,

pẹ̀lú ìdùnnú ayérayé ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.

Saamu 118

1  Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó dára;

àánú rẹ̀ dúró láéláé.

2 Jẹ́ kí Israẹli wí pé:

“Àánú rẹ̀ dúró láéláé”.

3 Jẹ́ kí ilé Aaroni wí pé:

“Àánú rẹ̀ dúró láéláé”.

4 Jẹ́ kí àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa wí pé:

“Àánú rẹ̀ dúró láéláé.”

5 Nínú ìrora mi, mo sọkún sí Olúwa,

ó sì dá mi lóhùn nípa pé ó tú mi sílẹ̀.

6 Olúwa ń bẹ fún èmi; èmi kì yóò bẹ̀rù.

Kí ni ènìyàn lè ṣe sí mi?

7 Olúwa ń bẹ fún mi; òun ni olùrànlọ́wọ́ mi.

Nítorí náà ni èmi ó ṣe rí ìṣẹ́gun mi lórí àwọn tí ó kórìíra mi.

8 Ó dára láti máa gbẹ́kẹ̀lé Olúwa

ju àti gbẹ́kẹ̀lé ènìyàn lọ.

9 Ó dára láti máa gbẹ́kẹ̀lé Olúwa

ju à ti gbẹ́kẹ̀lé àwọn ọmọ-aládé lọ.

10 Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yí mi káàkiri,

ṣùgbọ́n ní orúkọ Olúwa èmi gé wọn kúrò.

11 Wọ́n yí mi káàkiri ní gbogbo ẹ̀gbẹ́,

ṣùgbọ́n ní orúkọ Olúwa èmi gé wọn dànù.

12 Wọ́n gbá yìn ìn yí mi ká bí oyin,

ṣùgbọ́n wọ́n kú kíákíá bí iná ẹ̀gún;

ní orúkọ Olúwa èmi ké wọn dànù.

13 Ìwọ tì mí gidigidi kí n lè ṣubú,

ṣùgbọ́n Olúwa ràn mí lọ́wọ́.

14 Olúwa ni agbára àti orin mi;

ó sì di ìgbàlà mi.

15 Ohùn ayọ̀ àti ìgbàlà ń bẹ nínú àgọ́ àwọn olódodo:

“Ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ń ṣe ohun agbára!

16 Ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ní a gbéga;

ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ń ṣe ohun agbára!”

17 Èmi kì yóò kú, ṣùgbọ́n èmi yóò yè,

èmi yóò pòkìkí ohun tí Olúwa ṣe.

18 Olúwa bá mi wí gidigidi,

ṣùgbọ́n òun kò fi mí lé ikú lọ́wọ́.

19 Ṣí ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà òdodo fún mi:

èmi yóò bá ibẹ̀ wọlé, èmi yóò sì fi ọpẹ́ fún Olúwa.

20 Èyí ni ìlẹ̀kùn Olúwa

ibẹ̀ ni àwọn olódodo yóò bá wọlé.

21 Èmi yóò fi ọpẹ́ fún ọ, nítorí ó dá mi lóhùn;

ìwọ sì di ìgbàlà mi.

22  Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀,

ni ó di pàtàkì igun ilé;

23 Olúwa ti ṣe èyí,

ó ṣe ìyanu ní ojú wa.

24 Èyí ni ọjọ́ tí Olúwa dá:

ẹ jẹ́ kí ayọ̀ kí inú wa sì máa dùn nínú rẹ̀.

25 Olúwa, gbà wá;

Olúwa, fún wa ní àlàáfíà.

26 Ìbùkún ni ẹni tí ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa.

Àwa ti fi ìbùkún fún ọ láti ilé Olúwa wá.

27 Olúwa ni Ọlọ́run,

ó ti mú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tàn sí wa lára

pẹ̀lú ẹ̀ka igi ní ọwọ́, ó dára pọ̀ mọ́

ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń wọ́ nínú ayọ̀

ẹ fi okùn di ẹbọ náà mọ́ ìwo pẹpẹ.

28 Ìwọ ni Ọlọ́run mi, èmi yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ;

ìwọ ni Ọlọ́run mi, èmi yóò gbé ọ ga.

29 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun;

nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

Saamu 110

Ti Dafidi. Saamu.

1 Olúwa sọ fún Olúwa mi pé,

“Ìwọ jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi,

títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ

di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.”

2 Olúwa yóò na ọ̀pá agbára rẹ̀

láti Sioni wá, ìwọ jẹ ọba láàrín àwọn ọ̀tá rẹ.

3 Àwọn ènìyàn rẹ jẹ́ ọ̀rẹ́ àtinúwá

ní ọjọ́ ìjáde ogun rẹ, nínú ẹwà mímọ́,

láti inú òwúrọ̀ wá ìwọ ni ìrì ẹwà rẹ.

4 Olúwa ti búra,

kò sì í yí ọkàn padà pé,

“Ìwọ ni àlùfáà,

ní ipasẹ̀ Melkisedeki.”

5 Olúwa, ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni

yóò lu àwọn ọba bolẹ̀ ni ọjọ́ ìbínú rẹ̀.

6 Yóò ṣe ìdájọ́ láàrín kèfèrí,

yóò kún ibùgbé wọn pẹ̀lú òkú ara;

yóò fọ́n àwọn olórí ká sí orí ilẹ̀ ayé tí ó gbòòrò.

7 Yóò mu nínú odò ṣíṣàn ní ọ̀nà:

nítorí náà ni yóò ṣe gbé orí sókè.