Dafidi ní En-Gedi

1058 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

1 Samuẹli 23:29–24:22

29 Dafidi sì gòkè láti ibẹ̀ lọ, ó sì jókòó níbi tí ó sá pamọ́ sí ní En-Gedi.

24:1 Nígbà tí Saulu padà kúrò lẹ́yìn àwọn Filistini a sì sọ fún un pé, “Wò ó, Dafidi ń bẹ́ ni aginjù En-Gedi.” 2 Saulu sì mú ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) akọni ọkùnrin tí a yàn nínú gbogbo Israẹli ó sì lọ láti wá Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ lórí òkúta àwọn ewúrẹ́ igbó.

3 Ó sì dé ibi àwọn agbo àgùntàn tí ó wà ní ọ̀nà, ihò kan sì wà níbẹ̀, Saulu sì wọ inú rẹ̀ lọ láti bo ẹsẹ̀ rẹ̀, Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì ń bẹ lẹ́bàá ihò náà. 4 Àwọn ọmọkùnrin Dafidi sì wí fún un pé, “Wò ó, èyí ni ọjọ́ náà tí Olúwa wí fún ọ pé, ‘Wò ó, èmi fi ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́, ìwọ ó sì ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ lójú rẹ.’ ” Dafidi sì dìde, ó sì yọ́ lọ gé etí aṣọ Saulu.

5 Ó sì ṣe lẹ́yìn èyí, àyà já Dafidi nítorí tí ó gé etí aṣọ Saulu. 6 Òun sì wí fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pé, “Èèwọ̀ ni fún mi láti ọ̀dọ́ Olúwa wá bí èmi bá ṣe nǹkan yìí sí ẹni tí a ti fi àmì òróró Olúwa yàn, láti nawọ́ mi sí i, nítorí pé ẹni àmì òróró Olúwa ni.” 7 Dafidi sì fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí dá àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ dúró, kò sì jẹ́ kí wọn dìde sí Saulu, Saulu sì dìde kúrò ní ihò náà, ó sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ.

8 Dafidi sì dìde lẹ́yìn náà, ó sì jáde kúrò nínú ihò náà ó sì kọ sí Saulu pé, “Olúwa mi, ọba!” Saulu sì wo ẹ̀yìn rẹ̀. Dafidi sì dojú rẹ́ bo ilẹ̀ ó sì tẹríba fún un. 9 Dafidi sì wí fún Saulu pé, “Èéha ti ṣe tí ìwọ fi ń gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn pé, ‘Wò ó, Dafidi ń wa ẹ̀mí rẹ́’? 10 Wò ó, ojú rẹ́ rí i lónìí, bí Olúwa ti fi ìwọ lé mi lọ́wọ́ lónìí nínú ihò, àwọn kan ní kí èmi ó pa ọ, ṣùgbọ́n èmi dá ọ sí, ‘Èmi sì wí pé, èmi kì yóò nawọ́ mi sí olúwa mi, nítorí pé ẹni àmì òróró Olúwa ni òun jẹ́.’ 11 Pẹ̀lúpẹ̀lú, baba mi, wò ó, àní wo etí aṣọ rẹ lọ́wọ́ mi; nítorí èmi gé etí aṣọ rẹ, èmi kò sì pa ọ́, sì wò ó, kí o sì mọ̀ pé kò sí ibi tàbí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ mi, èmi kò sì ṣẹ̀ ọ̀, ṣùgbọ́n ìwọ ń dọdẹ ẹ̀mí mi láti gbà á. 12 Kí Olúwa ṣe ìdájọ́ láàrín èmi àti ìwọ, àti kí Olúwa ó gbẹ̀san mi lára rẹ; ṣùgbọ́n, ọwọ́ mi kì yóò sí lára rẹ. 13 Gẹ́gẹ́ bí òwe ìgbà àtijọ́ ti wí, ìwà búburú a máa ti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn búburú jáde wá; ṣùgbọ́n ọwọ́ mi kì yóò sí lára rẹ.

14 “Nítorí ta ni ọba Israẹli fi jáde? Ta ni ìwọ ń lépa? Òkú ajá, tàbí eṣinṣin? 15 Kí Olúwa ó ṣe onídàájọ́, kí ó sì dájọ́ láàrín èmi àti ìwọ, kí ó sì gbèjà mi, kí ó sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ rẹ.”

16 Ó sì ṣe, nígbà tí Dafidi sì dákẹ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún Saulu, Saulu sì wí pé, “Ohùn rẹ ni èyí bí, Dafidi ọmọ mi?” Saulu sì gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sọkún. 17 Ó sì wí fún Dafidi pé, “Ìwọ ṣe olódodo jù mí lọ; nítorí pé ìwọ ti fi ìre san án fún mi, èmi fi ibi san án fún ọ. 18 Ìwọ sì fi oore tí ìwọ ti ṣe fún mi hàn lónìí: nígbà tí ó jẹ́ pé, Olúwa ti fi ẹ̀mí mi lé ọ lọ́wọ́, ìwọ kò sì pa mí. 19 Nítorí pé bí ènìyàn bá rí ọ̀tá rẹ̀, ó lè jẹ́ kí ó lọ ní àlàáfíà bí? Olúwa yóò sì fi ìre san èyí ti ìwọ ṣe fún mi lónìí. 20 Wò ó, èmi mọ̀ nísinsin yìí pé, nítòótọ́ ìwọ ó jẹ ọba, àti pé ìjọba Israẹli yóò sì fi ìdí múlẹ̀ ní ọwọ́ rẹ. 21 Sì búra fún mi nísinsin yìí ní orúkọ Olúwa, pé, ìwọ kì yóò gé irú-ọmọ mi kúrò lẹ́yìn mi, àti pé, ìwọ kì yóò pa orúkọ mi run kúrò ní ìdílé baba mi.”

22 Dafidi sì búra fún Saulu. Saulu sì lọ sí ilé rẹ̀; ṣùgbọ́n Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì gòkè lọ sí ihò náà.

Saamu 57–58

Fún adarí orin. Ní ohùn “Má ṣe parun.” Ti Dafidi. Miktamu. Nígbà tí ó sá níwájú Saulu lọ sínú ihò òkúta.

1 Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, ṣàánú fún mi,

nítorí nínú rẹ ni ààbò ọkàn mí wà.

Èmi o fi ààbò mí sí ibi ìyẹ́ apá rẹ

títí tí ewu yóò fi kọjá lọ.

2 Mo kígbe sókè sí Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo jùlọ,

sí Ọlọ́run tó ń pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́ fún mi.

3 Òun yóò ránṣẹ́ láti ọ̀run wá,

yóò sì gbà mí, bí ẹni tí ń fẹ́ gbé mi mì

tilẹ̀ ń kẹ́gàn mi.

Ọlọ́run yóò rán àánú rẹ̀ àti òdodo rẹ̀ jáde.

4 Mo wà ní àárín àwọn kìnnìún;

mo dùbúlẹ̀ ni abẹ́ àwọn ẹ̀dá búburú,

àwọn ènìyàn tí eyín wọn dàbí ọ̀kọ̀ àti ọfà

ẹni tí ahọ́n rẹ̀ jẹ́ idà mímú.

5 Kí a yìn ọ́ Ọlọ́run, ju ọ̀run lọ,

kí ògo rẹ kò ju ti gbogbo ayé lọ.

6 Wọ́n ti ta àwọ̀n sílẹ̀ fún ẹsẹ̀ mi:

a tẹ orí ọkàn mi ba nínú ìtìjú,

wọ́n gbẹ́ kòtò sí ọ̀nà mi:

ṣùgbọ́n wọ́n ti jì síbẹ̀ fún ara wọn.

7  Ọkàn mi ti múra Ọlọ́run;

ọkàn mi ti múra, èmi ó kọrin, èmi ó si máa kọrin ìyìn.

8 Jí, ìwọ ọkàn mi!

Jí, ohun orin èlò àti dùùrù!

Èmi tìkára mi, yóò sì jí ní kùtùkùtù.

9 Èmi ó máa yìn ọ́, Olúwa, láàrín àwọn orílẹ̀-èdè;

èmi ó máa kọrin sí ọ láàrín àwọn ènìyàn.

10 Nítorí títóbi ní ìfẹ́ rẹ, tí ó dé ọ̀run;

òtítọ́ rẹ tàn dé àwọsánmọ̀.

11 Gbígbéga ni ọ́, Ọlọ́run, ju àwọn ọ̀run lọ;

kí ògo rẹ kí ó ju gbogbo ayé lọ.

Fún adarí orin. Tí ohùn “Má ṣe parun.” Ti Dafidi. Miktamu.

58:1 Ẹ̀yin ha ń sọ òdodo nítòótọ́

ẹ̀yin ìjọ ènìyàn?

Ǹjẹ́ ẹ̀yin ń ṣe ìdájọ́ tí ó ṣe títọ́

ẹ̀yìn ọmọ ènìyàn?

2 Bẹ́ẹ̀ kọ́, nínú ọkàn yín ẹ̀yìn ń gbèrò àìṣòdodo,

ọwọ́ yín sì tú ìwà ipá jáde ni ayé.

3 Ní inú ìyá wọn wá ni ènìyàn búburú tí ṣìnà,

lójúkan náà tí a ti bí wọn, wọn a máa ṣèké.

4 Oró wọn dàbí oró ejò,

wọn dàbí adití ejò paramọ́lẹ̀ tí ó di ara rẹ̀ ni etí,

5 tí kò ní gbọ́ ìpè àwọn atunilójú,

bí ó ti wù kí ó máa fi ọgbọ́n ṣe ìtujú tó.

6 Ká eyín ẹnu wọn, Ọlọ́run;

ní ẹnu wọn,

ká ọ̀gàn àwọn ọmọ kìnnìún, Olúwa.

7 Jẹ́ kí wọn parẹ́ bí omi tó ń sàn lọ;

nígbà tí ó bá fa ọfà rẹ̀, kí ọ̀kọ̀ wọn kí ó ṣẹ́.

8 Jẹ́ kí wọn rí bí ìgbín tí rẹ̀ dànù tí ó sì ṣègbé

bí ọmọ tí oṣù rẹ̀ kò pé, kí wọn má ṣe rí oòrùn.

9 Kí ìkòkò yín kí ó tó mọ ìgbóná ẹ̀gún;

bóyá ní tútù tàbí ní gbígbẹ, yóò fi ìjì gbá wọn lọ.

10 Olódodo yóò yọ̀ nígbà a bá ń gbẹ̀san wọn,

nígbà tí wọn bá wẹ ẹsẹ̀ wọn nínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn búburú.

11 Àwọn ènìyàn yóò wí pé,

“Lóòtítọ́ èrè àwọn ń bẹ fún olódodo;

lóòtítọ́ òun ni Ọlọ́run tí ń ṣe ìdájọ́ ní ayé.”

Saamu 63

Saamu ti Dafidi. Nígbà tí ó wà nínú aginjù Juda.

1 Ọlọ́run, ìwọ ni Ọlọ́run mi,

nígbà gbogbo ni mo ń ṣàfẹ́rí rẹ,

òǹgbẹ rẹ ń gbẹ ọkàn mi,

ara mi fà sí ọ,

ní ilẹ̀ gbígbẹ àti ilẹ̀ tí ń ṣàárẹ̀

níbi tí kò sí omi.

2 Èmi ti rí ọ ní ibi mímọ́,

mo rí agbára àti ògo rẹ.

3 Nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ayé lọ,

ètè mi yóò fògo fún ọ.

4 Èmi ó yìn ọ́ níwọ̀n ìgbà tí mo wà láààyè,

èmi ó gbé ọwọ́ sókè, èmi ó sì pe orúkọ rẹ.

5 A ó tẹ́ ọkàn mi lọ́rùn bí ọlọ́ràá oúnjẹ;

pẹ̀lú ètè ìyìn, ẹnu mi yóò yìn ọ́.

6 Nígbà tí mo rántí rẹ lórí ibùsùn mi;

èmi ń ronú rẹ títí ìṣọ́ òru.

7 Nítorí ìwọ ni ìrànlọ́wọ́ mi,

mo kọrin níbi òjìji ìyẹ́ apá rẹ.

8 Ọkàn mí fà sí ọ:

ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbé mi ró.

9 Àwọn tí ó ń wá ọkàn mí ni a ó parun;

wọn ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé.

10 Wọn ó ti ọwọ́ idà ṣubú

wọn ó sì di jíjẹ fún kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀.

11 Ṣùgbọ́n ọba yóò yọ̀ nínú Ọlọ́run

ẹni tí ó fi orúkọ Ọlọ́run búra yóò ṣògo

ṣùgbọ́n ẹnu àwọn òpùrọ́ la ó pamọ́.