Dafidi sá lọ sọ́dọ̀ Ahimeleki ní Nobu

1060 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

1 Samuẹli 21:1–9

1 Dafidi sì wá sí Nobu sọ́dọ̀ Ahimeleki àlùfáà, Ahimeleki sì bẹ̀rù láti pàdé Dafidi, ó sì wí fún un pé, “Èéha ti rí tí o fi ṣe ìwọ nìkan, àti tí kò sì sí ọkùnrin kan tí ó pẹ̀lú rẹ?”

2 Dafidi sì wí fún Ahimeleki àlùfáà pé, “Ọba pàṣẹ iṣẹ́ kan fún mi, ó sì wí fún mi pé, ‘Má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan mọ ìdí iṣẹ́ náà ti mo rán ọ, àti èyí tí èmi ti pàṣẹ fún ọ.’ Èmi sì yan àwọn ìránṣẹ́ mi sí ibí báyìí. 3 Ǹjẹ́ kín ni ó wà ní ọwọ́ rẹ̀? Fún mi ni ìṣù àkàrà márùn-ún tàbí ohunkóhun tí o bá rí.”

4 Àlùfáà náà sí dá Dafidi lóhùn ó sì wí pé, “Kò sí àkàrà mìíràn lọ́wọ́ mi bí kò ṣe àkàrà mímọ́. Kìkì pé bi àwọn ọmọkùnrin bá ti pa ara wọn mọ́ kúrò lọ́dọ̀ obìnrin!”

5 Dafidi sì dá àlùfáà náà lóhùn, ó sì wí fún un pé, “Nítòótọ́ ni a tí ń pa ara wá mọ́ kúrò lọ́dọ̀ obìnrin láti ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́ta wá, tí èmí ti jáde. Gbogbo nǹkan àwọn ọmọkùnrin náà ni ó mọ́, àti àkàrà náà sì wá dàbí àkàrà mìíràn, pàápàá nígbà tí ó jẹ́ pé òmíràn wà tí a yà sí mímọ́ lónìí nínú ohun èlò náà!” 6 Bẹ́ẹ̀ ni àlùfáà náà sì fi àkàrà mímọ́ fún un; nítorí tí kò sí àkàrà mìíràn níbẹ̀ bí kò ṣe àkàrà ìfihàn tí a ti kó kúrò níwájú Olúwa, láti fi àkàrà gbígbóná síbẹ̀ ní ọjọ́ tí a kó o kúrò.

7 Ọkùnrin kan nínú àwọn ìránṣẹ́ Saulu sì ń bẹ níbẹ̀ lọ́jọ́ náà, tí a tí dádúró síwájú Olúwa; orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Doegi, ará Edomu olórí nínú àwọn darandaran Saulu.

8 Dafidi sì tún wí fún Ahimeleki pé, “Kò sí ọ̀kọ̀ tàbí idà lọ́wọ́ rẹ níhìn-ín? Nítorí tí èmi kò mú idà mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò mú nǹkan ìjà mi lọ́wọ́, nítorí pé iṣẹ́ ọba náà jẹ́ iṣẹ́ ìkánjú.”

9 Àlùfáà náà sì wí pé, “Idà Goliati ará Filistini tí ó pa ní àfonífojì Ela ní ń bẹ, wò ó, a fi aṣọ kan wé e lẹ́yìn efodu; bí ìwọ yóò bá mú èyí, mú un; kò sì sí òmíràn níhìn-ín mọ́ bí kò ṣe ọ̀kan náà.”

Dafidi sì wí pé, “Kò sí èyí tí ó dàbí rẹ̀ fún mi.”

Dafidi sá lọ sọ́dọ̀ Akiṣi, ọba Gati

1 Samuẹli 21:10–15

10 Dafidi sì dìde, o sì sá ni ọjọ́ náà níwájú Saulu, ó sì lọ sọ́dọ̀ Akiṣi, ọba Gati. 11  Àwọn ìránṣẹ́ Akiṣi sì wí fún un pé, “Èyí ha kọ́ ní Dafidi ọba ilẹ̀ náà? Ǹjẹ́ wọn kò ha ti dárin ti wọ́n sì gbe orin nítorí rẹ̀, tí wọ́n sì jó pé,

“ ‘Saulu pa ẹgbẹ̀rún tirẹ̀.

Dafidi sì pa ẹgbàárùn-ún tirẹ̀’?”

12 Dafidi sì pa ọ̀rọ̀ wọ̀nyí í mọ́ ni ọkàn rẹ̀, ó sì bẹ̀rù Akiṣi ọba Gati gidigidi. 13  Òun sì pa ìṣe rẹ̀ dà níwájú wọn, ó sì sọ ara rẹ̀ di aṣiwèrè ní ọwọ́ wọn, ó sì ń fi ọwọ́ rẹ̀ ha ìlẹ̀kùn ojú ọ̀nà, ó sì ń wá itọ́ sí irùngbọ̀n rẹ̀.

14 Nígbà náà ni Akiṣi wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Wó o, nítorí kín ni ẹ̀yin ṣe mú un tọ̀ mí wá. 15 Mo ha ni un fi aṣiwèrè ṣe? Tí ẹ̀yin fi mú èyí tọ̀ mí wá láti hu ìwà aṣiwèrè níwájú mi? Eléyìí yóò ha wọ inú ilé mi?”

Saamu 56

Fún adarí orin. Ti ohùn “Àdàbà lórí Óákù òkè réré.” Ti Dafidi. Miktamu. Nígbà tí àwọn ará Filistini ka mọ́ ní Gati.

1 Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run,

nítorí àwọn ènìyàn ń fi ìgbónára lépa mi;

ní gbogbo ọjọ́ ni wọn ń kọjú ìjà sí mi, wọn ń ni mi lára.

2 Àwọn ọ̀tá mi ń lé mi ní gbogbo ọjọ́,

àwọn ènìyàn ń kọjú ìjà sí mi nínú ìgbéraga wọn.

3 Nígbà tí ẹ̀rù bà ń bà mí,

èmi o gbẹ́kẹ̀lé ọ.

4 Nínú Ọlọ́run èmi yóò máa yìn ọ̀rọ̀ rẹ,

nínú Ọlọ́run ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi; ẹ̀rù kì yóò bà mí

kí ni ẹran-ara lè ṣe sí mi?

5 Wọn ń yí ọ̀rọ̀ mí ní gbogbo ọjọ́,

wọn ń gbèrò nígbà gbogbo láti ṣe mí níbi.

6 Wọn kó ara wọn jọ, wọ́n ba.

Wọ́n ń ṣọ́ ìgbésẹ̀ mi

wọn ń làkàkà láti gba ẹ̀mí mi.

7 San ẹ̀san iṣẹ́ búburú wọ́n fún wọn;

ní ìbínú rẹ, Ọlọ́run, wọ́ àwọn ènìyàn náà bọ́ sílẹ̀.

8 Kọ ẹkún mi sílẹ̀;

kó omijé mi sí ìgò rẹ,

wọ́n kò ha sí nínú ìkọ̀sílẹ̀ rẹ bí?

9 Nígbà náà ni àwọn ọ̀tá mi yóò pẹ̀yìndà

nígbà tí mo bá pè fún ìrànlọ́wọ́

nípa èyí ni mo mọ̀ pé Ọlọ́run ń bẹ fún mi.

10 Nínú Ọlọ́run, ẹni tí mo yìn ọ̀rọ̀ rẹ̀

nínú Olúwa, ẹni tí mo yin ọ̀rọ̀ rẹ̀,

11 nínú Ọlọ́run ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi:

ẹ̀rù kì yóò bà mí.

Kí ni ènìyàn lè ṣe sí mi?

12 Mo jẹ́ ẹ̀jẹ́ lábẹ́ rẹ Ọlọ́run:

èmi o mú ìyìn mi wá fún ọ.

13 Nítorí ìwọ tí gbà mí lọ́wọ́ ikú

àti ẹsẹ̀ mi lọ́wọ́ ìṣubú,

kí èmí lè máa rìn níwájú Ọlọ́run

ní ìmọ́lẹ̀ àwọn alààyè.

Saamu 34

Tí Dafidi. Nígbà tí ó díbọ́n bí ẹni tí ń ṣe wèrè níwájú Abimeleki, ẹni tí ó lé e lọ, ó sì jáde lọ.

1 Èmi yóò máa fi ìbùkún fún Olúwa nígbà gbogbo;

ìyìn rẹ̀ yóò máa wà ní ẹnu mi títí láé.

2 Ọkàn mí yóò máa ṣògo nínú Olúwa;

jẹ́ kí àwọn onírẹ̀lẹ̀ gbọ́ kí inú wọn kí ó sì máa dùn.

3 Gbé Olúwa ga pẹ̀lú mi;

kí ẹ sì jẹ́ kí a jọ gbé orúkọ rẹ̀ lékè.

4 Èmi wá Olúwa, ó sì dá mi lóhùn;

Ó sì gbà mí kúrò nínú ìbẹ̀rù mi gbogbo.

5 Wọ́n wò ó, ìmọ́lẹ̀ sì mọ́ wọn;

ojú kò sì tì wọ́n.

6 Ọkùnrin olùpọ́njú yí kígbe, Olúwa sì gbóhùn rẹ̀;

ó sì gbà á là kúrò nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.

7 Angẹli Olúwa yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká

ó sì gbà wọ́n.

8 Tọ́ ọ wò kí o sì rí i wí pé Olúwa dára;

ẹni ayọ̀ ni ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ààbò nínú rẹ̀.

9 Ẹ bẹ̀rù Olúwa, ẹ̀yin ènìyàn rẹ̀ mímọ́,

nítorí pé kò sí àìní fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.

10 Àwọn ọmọ kìnnìún a máa ṣe aláìní ebi a sì máa pa wọ́n;

ṣùgbọ́n àwọn tí ó wá Olúwa kì yóò ṣe aláìní ohun tí ó dára.

11 Wá, ẹ̀yin ọmọ mi, fi etí sí mi;

èmi yóò kọ́ ọ yín ní ẹ̀rù Olúwa.

12  Ta ni nínú yín tí ń fẹ́ ìyè, tí ó sì ń fẹ́ ọjọ́ púpọ̀;

kí ó lè gbádùn ọjọ́ rere?

13 Pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi

àti ètè rẹ̀ kúrò ní ẹ̀tàn sísọ.

14 Yà kúrò nínú ibi kí o sì ṣe rere;

wá àlàáfíà, kí o sì lépa rẹ̀.

15 Ojú Olúwa ń bẹ lára àwọn olódodo;

etí i rẹ̀ sì ṣí sí ẹkún wọn.

16 Ojú Olúwa korò sí àwọn tí ń ṣe búburú;

láti ké ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀.

17 Nígbà tí olódodo bá ké fún ìrànlọ́wọ́,

Olúwa a máa gbọ́, a sì yọ wọ́n jáde láti inú gbogbo wàhálà wọn.

18 Olúwa súnmọ́ etí ọ̀dọ̀ àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn;

ó sì gba irú àwọn tí í ṣe oníròra ọkàn là.

19 Ìpọ́njú àwọn olódodo pọ̀,

ṣùgbọ́n Olúwa gbà wọ́n kúrò nínú gbogbo rẹ̀.

20 Ó pa gbogbo egungun wọn mọ́;

kò sí ọ̀kan tí ó dá nínú wọn.

21 Ibi ni ó mú ikú ìkà wá,

àti àwọn tí ó kórìíra olódodo ni yóò jẹ̀bi.

22 Olúwa ra ọkàn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ padà;

kò sí ọ̀kan nínú àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé tí yóò jẹ̀bi.