Dafidi ní Mispa (continued)

1060 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Saamu 140

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

1 Olúwa, gbà mi lọ́wọ́ ọkùnrin búburú u nì,

yọ mí lọ́wọ́ ọkùnrin ìkà a nì,

2 ẹni tí ń ro ìwà búburú ní inú wọn;

nígbà gbogbo ni wọ́n ń rú ìjà sókè sí mi.

3 Wọ́n ti pọ́n ahọ́n wọn bí ejò,

oró paramọ́lẹ̀ ń bẹ ní abẹ́ ètè wọn.

4 Olúwa, pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú;

yọ mí kúrò lọ́wọ́ ọkùnrin ìkà a nì

ẹni tí ó ti pinnu rẹ̀ láti bi ìrìn mi ṣubú.

5 Àwọn agbéraga ti dẹkùn sílẹ̀ fún mi àti okùn:

wọ́n ti na àwọ̀n lẹ́bàá ọ̀nà;

wọ́n ti kẹ́kùn sílẹ̀ fún mi.

6 Èmi wí fún Olúwa pé ìwọ ni Ọlọ́run mi;

Olúwa, gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.

7 Olúwa Olódùmarè, agbára ìgbàlà mi,

ìwọ ni ó bo orí mi mọ́lẹ̀ ní ọjọ́ ìjà.

8 Olúwa, máa ṣe fi ìfẹ́ ènìyàn búburú fún un;

má ṣe kún ọgbọ́n búburú rẹ̀ lọ́wọ́;

kí wọn kí ó máa ba à gbé ara wọn ga. Sela.

9 Bí ó ṣe ti orí àwọn tí ó yí mi káàkiri ni,

jẹ́ kí ète ìka ara wọn kí ó bò wọ́n mọ́lẹ̀.

10 A ó da ẹ̀yin iná sí wọn lára,

Òun yóò wọ́ wọn lọ sínú iná,

sínú ọ̀gbun omi jíjìn,

kí wọn kí ó má ba à le dìde mọ́.

11 Má ṣe jẹ́ kí aláhọ́n búburú fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ ní ayé;

ibi ni yóò máa dọdẹ ọkùnrin ìkà nì láti bì í ṣubú.

12 Èmi mọ̀ pé, Olúwa yóò mú ọ̀nà olùpọ́njú dúró,

yóò sì ṣe ẹ̀tọ́ fún àwọn tálákà.

13 Nítòótọ́ àwọn olódodo yóò

máa fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ;

àwọn ẹni dídúró ṣinṣin yóò máa gbé iwájú rẹ.

Saamu 35

Ti Dafidi.

1 Olúwa, gbógun ti àwọn tí ń gbóguntì mí;

kí o sì kọ ojú ìjà sí àwọn tí ó ń bá mi í jà!

2 Di asà àti àpáta mú,

kí o sì dìde fún ìrànlọ́wọ́ mi!

3 Fa idà àti ọ̀kọ̀ yọ

kí o sì dojúkọ àwọn tí ń lé mi.

Sọ fún ọkàn mi pé,

“Èmi ni ìgbàlà rẹ.”

4 Kí wọn kí ó dààmú,

kí a sì ti àwọn tí ń lépa ọkàn mi lójú;

kí a sì mú wọn padà,

kí a sì dààmú àwọn tí ń gbèrò ìpalára mi.

5 Jẹ́ kí wọn dàbí ìyàngbò níwájú afẹ́fẹ́,

kí angẹli Olúwa kí ó máa lé wọn kiri.

6 Jẹ́ kí ọ̀nà wọn kí ó ṣókùnkùn, kí ó sì máa yọ́,

kí angẹli Olúwa kí ó máa lépa wọn!

7 Nítorí pé, ní àìnídìí ni wọ́n dẹ àwọ̀n wọn sílẹ̀ fún mi,

ní àìnídìí ni wọ́n wa kòtò sílẹ̀ fún ọkàn mi.

8 Kí ìparun kí ó wá sí orí rẹ̀ ní òjijì.

Àwọ̀n rẹ̀ tí ó dẹ, kí ó mú òun tìkára rẹ̀;

kí wọn ṣubú sínú kòtò sí ìparun ara rẹ̀.

9 Nígbà náà ni ọkàn mi yóò yọ̀ nínú Olúwa,

àní, yóò sì máa yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ̀.

10 Gbogbo egungun mi yóò wí pé,

“Ta ni ó dàbí ì ìwọ Olúwa?

O gba tálákà lọ́wọ́ àwọn tí ó lágbára jù ú lọ,

tálákà àti aláìní lọ́wọ́ ẹni tí ń fi ṣe ìkógun?”

11 Àwọn ẹlẹ́rìí èké dìde;

wọ́n ń bi mi ní ohun tí èmi kò mọ̀.

12 Wọ́n fi búburú san ìre fún mi;

láti sọ ọkàn mi di òfo.

13 Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi ni, nígbà tí wọn ń ṣe àìsàn, mo wọ aṣọ ọ̀fọ̀;

mo fi àwẹ̀ pọ́n ara mi lójú.

Mo gba àdúrà pẹ̀lú ìtẹríba ní oókan àyà mi;

14 èmí ń lọ kiri bí ẹni ń ṣọ̀fọ̀

bí i ẹni wí pé fún ọ̀rẹ́ tàbí ẹ̀gbọ́n mi ni.

Èmí tẹríba nínú ìbànújẹ́

bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ìyà rẹ̀.

15 Ṣùgbọ́n nínú ìkọ̀sẹ̀ mi wọ́n sì yọ̀, wọ́n sì kó ara wọn jọ;

wọ́n kó ara wọn jọ sí mi; àní àwọn tí èmi kò mọ̀.

Wọ́n fà mí ya wọ́n kò sì dákẹ́.

16 Bí àwọn àgàbàgebè tí ń ṣe ẹlẹ́yà ní àpèjẹ

wọ́n pa eyín wọn keke sí mi.

17 Yóò ti pẹ́ tó Olúwa, tí ìwọ yóò máa wò wọ́n lọ?

Yọ mí kúrò nínú ìparun wọn,

àní ẹ̀mí ì mi kúrò lọ́wọ́ kìnnìún.

18 Nígbà náà ni èmi yóò ṣọpẹ́ fún Ọ nínú àjọ ńlá;

èmi yóò máa yìn Ọ́ ní àwùjọ ọ̀pọ̀ ènìyàn.

19  Má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi

kí ó yọ̀ lórí ì mi;

bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe àwọn tí ó kórìíra mi

ní àìnídìí máa ṣẹ́jú sí mi.

20 Nítorí pé wọn kò sọ ọ̀rọ̀ àlàáfíà,

ṣùgbọ́n wọ́n lóyún ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn

sí àwọn ènìyàn dídákẹ́ ilẹ̀ náà.

21 Wọ́n ya ẹnu wọn gbòòrò sí mi; wọ́n wí pé, “Háà! Háà!

Ojú wa sì ti rí i.”

22 Ìwọ́ ti rí i Olúwa; má ṣe dákẹ́!

Olúwa má ṣe jìnnà sí mi!

23 Dìde! ru ara rẹ̀ sókè fún ààbò mi,

àti sí ọ̀ràn mi, Ọlọ́run mi àti Olúwa mi!

24 Ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa Ọlọ́run mi, gẹ́gẹ́ bí òdodo rẹ,

kí o má sì ṣe jẹ́ kí wọn kí ó yọ̀ lórí mi!

25 Má ṣe jẹ́ kí wọn wí nínú ara wọn pé, “Háà! A ti rí ohun tí ọkàn wa ń fẹ́!”

Má ṣe jẹ́ kí wọn kí ó wí pé, “A ti gbé e mì.”

26 Kí ojú kí ó tì wọ́n,

kí wọn kí ó sì dààmú pọ̀,

àní àwọn tí ń yọ̀ sí ìyọnu mi

kí a fi ìtìjú àti àbùkù wọ̀ wọ́n ní aṣọ tí ń gbéraga sí mi.

27 Jẹ́ kí àwọn tí ó fẹ́ ìdáláre mi

fò fún ayọ̀ àti ìdùnnú;

kí wọn máa sọ ọ́ títí lọ, “Pé gbígbéga ni Olúwa,

sí àlàáfíà ìránṣẹ́ rẹ̀.”

28 Nígbà náà ni ahọ́n mi yóò máa sọ̀rọ̀ òdodo rẹ,

àti ìyìn rẹ ní gbogbo ọjọ́.

Saamu 64

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

1 Gbóhùn mi, Ọlọ́run, bí mo ti ń sọ àròyé mi

pa ọkàn mi mọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀rù àwọn ọ̀tá.

2 Pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ àwọn ènìyàn búburú

kúrò nínú ọ̀pọ̀ igbe lọ́wọ́ ìrúkèrúdò oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.

3 Wọ́n pọ́n ahọ́n wọn bí idà,

wọ́n sì fa ọrun wọn le láti tafà wọn, àní ọ̀rọ̀ kíkorò.

4 Wọ́n tafà ní ìkọ̀kọ̀ sí àwọn aláìlẹ́ṣẹ̀:

wọ́n tafà si lójijì, wọn kò sì bẹ̀rù.

5 Wọ́n, gba ara wọn níyànjú nínú èrò búburú,

wọ́n sọ̀rọ̀ lórí dídẹkùn sílẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀

wọ́n wí pé, “Ta ni yóò rí wa?”

6 Wọ́n gbìmọ̀ àìṣòdodo, wọ́n wí pé,

“A wa ti parí èrò tí a gbà tán!”

Lóòótọ́ àyà àti ọkàn ènìyàn kún fún àrékérekè.

7 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ta wọ́n ní ọfà;

wọn ó sì gbọgbẹ́ lójijì.

8 Ahọ́n wọn yóò sì dojú ìjà kọ wọ́n, yóò sì run wọ́n,

gbogbo ẹni tí ó bá rí wọn yóò sì mi orí fún wọn.

9 Gbogbo ènìyàn yóò máa bẹ̀rù

wọn ó kéde iṣẹ́ Ọlọ́run

wọn ó dúró lé ohun tí ó ṣe.

10 Jẹ́ kí olódodo kí ó yọ̀ nínú Olúwa

yóò sì rí ààbò nínú rẹ̀.

Gbogbo ẹni ìdúró ṣinṣin ní ọkàn yóò máa yìn ín.