Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Ìrẹ̀sílẹ̀ àti Ìgbéga Kristi

A sọ ìrẹ̀sílẹ̀, ìjìyà àti ìgbéga Kristi tẹ́lẹ̀.

710 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Isaiah 52:13–53:12

13 Kíyèsi i, ìránṣẹ́ mi yóò hùwà ọlọ́gbọ́n;

òun ni a ó gbé sókè tí a ó sì gbéga

a ó sì gbé e lékè gidigidi.

14 Gẹ́gẹ́ bí a ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí wọ́n ń bu ọlá fún un—

ìwò ojú rẹ ni a ti bàjẹ́ kọjá ti ẹnikẹ́ni àti ìrísí rẹ̀ ní a ti bàjẹ́ kọjá ohun tí ènìyàn ń fẹ́.

15  Bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe bomirin àwọn orílẹ̀-èdè ká,

àwọn ọba yóò sì pa ẹnu wọn mọ́ nítorí rẹ̀.

Nítorí ohun tí a kò sọ fún wọn, wọn yóò rí i,

àti ohun tí wọn kò tí ì gbọ́, ni yóò sì yé wọn.

53:1  Ta ni ó ti gba ìròyìn in wa gbọ́

àti ta ni a ti fi apá Olúwa hàn fún?

2 Òun dàgbàsókè níwájú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ irúgbìn,

àti gẹ́gẹ́ bí i gbòǹgbò tí ó jáde láti inú ìyàngbẹ ilẹ̀.

Òun kò ní ẹwà tàbí ògo láti fà wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀,

kò sí ohun kankan nínú àbùdá rẹ̀

tí ó fi yẹ kí a ṣàfẹ́rí i rẹ̀.

3 A kẹ́gàn rẹ̀ àwọn ènìyàn sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀,

ẹni ìbànújẹ́, tí ó sì mọ bí ìpọ́njú ti rí.

Gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan tí àwọn ènìyàn ń fojú pamọ́ fún

a kẹ́gàn rẹ, a kò sì bu ọlá fún un rárá.

4  Lóòtítọ́ ó ti ru àìlera wa lọ

ó sì ti ru ìbànújẹ́ wa pẹ̀lú,

síbẹ̀ a kà á sí ẹni tí Ọlọ́run lù,

tí ó lù, tí a sì pọ́n lójú.

5  Ṣùgbọ́n a sá a lọ́gbẹ́ nítorí àìṣedéédéé wa

a pa á lára nítorí àìṣòdodo wa;

ìjìyà tí ó mú àlàáfíà wá fún wa wà lórí i rẹ̀,

àti nípa ọgbẹ́ rẹ̀ ni a fi mú wa láradá.

6 Gbogbo wa bí àgùntàn, ti ṣìnà lọ,

ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ti yà sí ọ̀nà ara rẹ̀;

Olúwa sì ti gbé e ka orí ara rẹ̀

gbogbo àìṣedéédéé wa.

7  A jẹ ẹ́ ní yà, a sì pọ́n ọn lójú,

síbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀;

a mú un wá gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́-àgùntàn sọ́dọ̀ alápatà,

àti gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tí ó dákẹ́ níwájú olùrẹ́run rẹ̀,

síbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀.

8 Pẹ̀lú ìpọ́nlójú àti ìdánilẹ́jọ́ ni a mú un jáde lọ,

ta ni ó sì le sọ nípa ìrànlọ́wọ́ rẹ̀?

Nítorí a ké e kúrò ní ilẹ̀ àwọn alààyè;

nítorí àìṣedéédéé àwọn ènìyàn mi ni a ṣe lù ú.

9  A fún un ní ibojì pẹ̀lú àwọn ìkà,

àti pẹ̀lú àwọn ọlọ́rọ̀ ní ikú rẹ̀,

bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò hùwà jàgídíjàgan kan,

tàbí kí a rí ẹ̀tàn kan ní ẹnu rẹ̀.

10 Síbẹ̀, ó wu Olúwa láti pa á lára

àti láti mú kí ó jìyà,

bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa fi ayé rẹ̀

fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀,

Òun yóò rí àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ àti ọjọ́ ayé

rẹ̀ yóò pẹ́ títí,

àti ète Olúwa ni yóò gbèrú ní ọwọ́ rẹ̀.

11 Lẹ́yìn ìpọ́njú ẹ̀mí rẹ̀,

òun yóò rí ìmọ́lẹ̀, ààyè yóò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn;

nípa ìmọ̀ rẹ̀ ìránṣẹ́ mi olódodo yóò dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ láre,

Òun ni yóò sì ru àìṣedéédéé wọn.

12  Nítorí náà èmi yóò fún un ní ìpín pẹ̀lú àwọn ẹni ńlá

òun yóò sì pín ìkógun pẹ̀lú àwọn alágbára,

nítorí pé òun jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ fún ikú,

tí a sì kà á mọ́ àwọn alárékọjá.

Nítorí ó ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀,

ó sì ṣe ìlàjà fún àwọn alárékọjá.

Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Ìdàgbàsókè àti Ìṣẹ́gun Ìjọ

Isaiah 54

1  “Kọrin, ìwọ obìnrin àgàn,

ìwọ tí kò tí ì bímọ rí;

bú sí orin, ẹ hó fún ayọ̀,

ẹ̀yin tí kò tí ì rọbí rí;

nítorí pé púpọ̀ ni ọmọ àwọn obìnrin ìsọdahoro

ju ti ẹni tí ó ní ọkọ,”

ni Olúwa wí.

2 Fẹ ibi àgọ́ rẹ lójú sí i,

fẹ aṣọ àgọ́ rẹ kí ó gbòòrò sí i,

má ṣe dá a dúró;

sọ okùn rẹ di gígùn,

mú òpó rẹ lágbára sí i.

3 Nítorí ìwọ ó fẹ̀ sọ́tùn àti sí òsì;

ìrandíran rẹ yóò jogún àwọn orílẹ̀-èdè,

wọn yóò sì dó sí ahoro àwọn ìlú wọn.

4 “Má ṣe bẹ̀rù, ìtìjú kò ní ṣubú lù ọ́.

Má ṣe bẹ̀rù ìdójútì, a kì yóò kàn ọ́ lábùkù.

Ìwọ yóò gbàgbé ìtìjú ìgbà èwe e rẹ,

ìwọ kì yóò sì rántí ẹ̀gàn ìgba-opo rẹ mọ́.

5 Nítorí Ẹlẹ́dàá rẹ ni ọkọ rẹ

Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀

Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà rẹ;

a sì ń pè é ní Ọlọ́run gbogbo ayé.

6 Olúwa yóò pè ọ́ padà

àfi bí ẹni pé obìnrin tí a kọ̀sílẹ̀

tí a sì bà lọ́kàn jẹ́

obìnrin tí a fẹ́ ní ọ̀dọ́,

tí a sì wá jákulẹ̀,” ni Olúwa wí.

7 “Fún ìgbà díẹ̀ ni mo kọ̀ ọ́ sílẹ̀,

ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn ìyọ́nú èmi yóò

mú ọ padà wá.

8 Ní ríru ìbínú.

Mo fi ojú pamọ́ fún ọ fún ìṣẹ́jú kan,

ṣùgbọ́n pẹ̀lú àánú àìnípẹ̀kun

Èmi yóò síjú àánú wò ọ́,”

ni Olúwa Olùdáǹdè rẹ wí.

9 “Sí mi, èyí dàbí i àwọn ọjọ́ Noa,

nígbà tí mo búra pé àwọn omi

Noa kì yóò tún bo ilẹ̀ ayé mọ́.

Bẹ́ẹ̀ ni nísinsin yìí mo ti búra láti má ṣe bínú sí ọ,

bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá ọ wí mọ́.

10 Bí a tilẹ̀ mi àwọn òkè ńlá

tí a sì ṣí àwọn òkè kékeré nídìí,

síbẹ̀síbẹ̀ ìfẹ́ àìkùnà mi fún ọ kì yóò yẹ̀ láéláé

tàbí májẹ̀mú àlàáfíà ni a ó mú kúrò,”

ni Olúwa, ẹni tí ó síjú àánú wò ọ́ wí.

11  Ìwọ ìlú tí a pọ́n lójú, tí ìjì ń gbá kiri

tí a kò sì tù nínú,

Èmi yóò fi òkúta Tikuosi kọ́ ọ

àti ìpìlẹ̀ rẹ pẹ̀lú safire.

12 Èmi yóò fi iyùn ṣe odi rẹ,

àwọn ẹnu-ọ̀nà ni a ó fi ohun èlò dáradára fún,

àti àwọn ògiri rẹ pẹ̀lú òkúta iyebíye.

13  Gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ ni Olúwa yóò kọ́,

àlàáfíà àwọn ọmọ rẹ yóò jẹ́ ńlá àti púpọ̀.

14 Ní òdodo ni a ó fi ìdí rẹ kalẹ̀

ìwà ipá yóò jìnnà sí ọ

o kò ní bẹ̀rù ohunkóhun,

ìpayà la ó mú kúrò pátápátá;

kò ní súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ.

15 Bí ẹnikẹ́ni bá tilẹ̀ bá ọ jà, kò ní jẹ́ láti ọwọ́ mi;

ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ọ jà ni yóò túúbá fún ọ.

16 “Kíyèsi i, èmi ni ó dá alágbẹ̀dẹ

tí ń fẹ́ iná èédú iná

tí ó sì ń mú ohun èlò wá tí ó bá iṣẹ́ rẹ mu.

Èmi náà sì ni ẹni tí ó dá apanirun láti ṣe iṣẹ́ ibi;

17 kò sí ohun ìjà tí a ṣe sí ọ tí yóò lè ṣe nǹkan,

àti gbogbo ahọ́n tí ó dìde sí ọ ní ìdájọ́ ni ìwọ ó dá ní ẹ̀bi.

Èyí ni ogún àwọn ìránṣẹ́ Olúwa,

èyí sì ni ìdáláre wọn láti ọ̀dọ̀ mi,”

ni Olúwa wí.

Ọ̀pọ̀ Ìbùkún Ìhìnrere

Ọ̀pọ̀ yanturu àti ìtayọlọ́lá àwọn ìbùkún ìhìnrere.

Isaiah 55:1–56:8

1  “Ẹ wá, gbogbo ẹ̀yin tí òǹgbẹ ń gbẹ,

ẹ wá sí ibi omi;

àti ẹ̀yin tí kò ní owó;

ẹ wá, ẹ rà kí ẹ sì jẹ!

Ẹ wá ra wáìnì àti wàrà

láìsí owó àti láìdíyelé.

2 Èéṣe tí ẹ fi ń ná owó fún èyí tí kì í ṣe àkàrà

àti làálàá yín lórí ohun tí kì í tẹ́nilọ́rùn?

Tẹ́tí sílẹ̀, tẹ́tí sí mi, kí ẹ sì jẹ èyí tí ó dára,

bẹ́ẹ̀ ni ọkàn yín yóò láyọ̀ nínú ọrọ̀ tí ó bójúmu.

3  Tẹ́tí sílẹ̀ kí o sì wá sọ́dọ̀ mi;

gbọ́ tèmi, kí ọkàn rẹ lè wà láààyè.

Èmi yóò dá májẹ̀mú ayérayé pẹ̀lú rẹ,

ìfẹ́ òtítọ́ tí mo ṣèlérí fún Dafidi.

4 Kíyèsi i, mo ti fi òun ṣe ẹlẹ́rìí fún àwọn ènìyàn,

olórí àti apàṣẹ fún àwọn ènìyàn.

5 Lóòtítọ́ ìwọ yóò ké sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ kò mọ̀

àti orílẹ̀-èdè tí ìwọ kò mọ̀ ni yóò sáré tọ̀ ọ́ wá,

nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ

Ẹni Mímọ́ Israẹli

nítorí pé ó ti fi ohun dídára dá ọ lọ́lá.”

6 Ẹ wá Olúwa nígbà tí ẹ lè rí i;

ẹ pè é nígbà tí ó wà nítòsí.

7 Jẹ́ kí ìkà kí ó kọ ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀

àti ènìyàn búburú èrò rẹ̀.

Jẹ́ kí ó yípadà sí Olúwa, Òun yóò sì ṣàánú fún un,

àti sí Ọlọ́run wa, nítorí Òun yóò sì dáríjì.

8 “Nítorí èrò mi kì í ṣe èrò yín,

tàbí ọ̀nà yín a ha máa ṣe ọ̀nà mi,”

ni Olúwa wí.

9 “Gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti ga ju ayé lọ,

bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín lọ

àti èrò mi ju èrò yín lọ.

10  Gẹ́gẹ́ bí òjò àti yìnyín

ti wálẹ̀ láti ọ̀run

tí kì í sì padà sí ibẹ̀

láì bomirin ilẹ̀

kí ó sì mú kí ó tanná kí ó sì rudi,

tó bẹ́ẹ̀ tí yóò fi mú irúgbìn fún afúnrúgbìn

àti àkàrà fún ọ̀jẹun,

11 bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ mi tí ó jáde láti ẹnu mi wá;

kì yóò padà sọ́dọ̀ mi lọ́wọ́ òfo,

ṣùgbọ́n yóò ṣe ohun tí mo fẹ́,

yóò sì mú ète mi tí mo fi rán an wá sí ìmúṣẹ.

12 Ẹ̀yin yóò jáde lọ ní ayọ̀

a ó sì darí i yín lọ ní àlàáfíà;

òkè ńlá ńlá àti kéékèèké

yóò bú sí orin níwájú yín

àti gbogbo igi inú pápá

yóò máa pàtẹ́wọ́.

13 Dípò igi ẹ̀gún ni igi junifa yóò máa dàgbà,

àti dípò ẹ̀wọ̀n, maritili ni yóò yọ.

Èyí yóò wà fún òkìkí Olúwa,

fún àmì ayérayé,

tí a kì yóò lè parun.”

56:1 Èyí ni ohun ti Olúwa sọ:

“Ẹ pa ìdájọ́ mọ́

ẹ sì ṣe ohun tí ó tọ̀nà,

nítorí ìgbàlà mi súnmọ́ tòsí

àti òdodo mi ni a ó fihàn láìpẹ́ jọjọ.

2 Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣe èyí,

àti fún ọmọ ènìyàn tí ó dìímú ṣinṣin,

tí ó pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ láì bà á jẹ́,

tí ó sì pa ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi ṣíṣe.”

3 Má ṣe jẹ́ kí àjèjì kan tí ó ti di ara rẹ̀

mọ́ Olúwa sọ wí pé,

“Olúwa yóò yà mí sọ́tọ̀ kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.”

Àti kí ìwẹ̀fà kan ṣe àròyé pé,

“Igi gbígbẹ lásán ni mí.”

4 Nítorí pé báyìí ni Olúwa wí:

“Sí àwọn ìwẹ̀fà yìí tí ó pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́,

tí wọ́n yan ohun tí ó dùn mọ́ mi

tí wọ́n sì di májẹ̀mú mi mú ṣinṣin

5 fún wọn ni Èmi yóò fún nínú tẹmpili àti àgbàlá rẹ̀

ìrántí kan àti orúkọ kan

tí ó sàn ju àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin,

Èmi yóò fún wọn ní orúkọ ayérayé

tí a kì yóò ké kúrò.

6 Àti àwọn àjèjì tí ó so ara wọn mọ́ Olúwa

láti sìn ín,

láti fẹ́ orúkọ Olúwa

àti láti foríbalẹ̀ fún un

gbogbo àwọn tí ń pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ láì bà á jẹ́

àti tí wọ́n sì di májẹ̀mú mi mú ṣinṣin—

7  àwọn wọ̀nyí ni èmi yóò mú wá òkè mímọ́ mi,

èmi ó sì fún wọn ní ayọ̀ nínú ilé àdúrà mi.

Ẹbọ sísun wọn àti ìrúbọ wọn,

ni a ó tẹ́wọ́gbà lórí i pẹpẹ mi;

nítorí a ó máa pe ilé mi ní

ilé àdúrà fún gbogbo orílẹ̀-èdè.”

8 Olúwa Olódùmarè sọ wí pé—

ẹni tí ó kó àwọn àtìpó Israẹli jọ:

“Èmi yóò kó àwọn mìíràn jọ pẹ̀lú wọn

yàtọ̀ sí àwọn tí a ti kójọ.”