Amosi Sọtẹ́lẹ̀ Lòdì sí Àwọn Orílẹ̀-Èdè àti Israẹli (continued)
Amosi kéde ìdájọ́ lórí àwọn orílẹ̀-èdè aládùúgbò, àti lórí Israẹli àti Juda.
793 ṣáájú ìbí Kristi
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)
1 Gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ìwọ ilé Israẹli, ìpohùnréré ẹkún tí mo ṣe nípa rẹ:
2 “Wúńdíá Israẹli ṣubú
láì kò sì le padà dìde
ó di ẹni ìkọ̀tì ní ilẹ̀ rẹ̀
kò sí ẹni tí yóò gbé e dìde.”
3 Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí:
“Ìlú tí ẹgbẹ̀rún (1,000) alágbára ti jáde,
yóò dín ku ọgọ́rùn-ún ní Israẹli.
Ìlú tí ọgọ́rùn-ún alàgbà ti jáde
yóò ṣẹ́kù ẹni mẹ́wàá.”
4 Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún ilé Israẹli:
“Wá mi kí o sì yè;
5 ẹ má ṣe wá Beteli,
ẹ má ṣe lọ sí Gilgali,
ẹ má ṣe rìnrìn àjò lọ sí Beerṣeba.
Nítorí dájúdájú a ó kó Gilgali ní ìgbèkùn,
A ó sì sọ Beteli di asán.”
6 Ẹ wá Olúwa, ẹ̀yin yóò sì yè,
kí ó má ba à gbilẹ̀ bí iná ní Josẹfu
a sì jó o run
Beteli kò sì ní rí ẹni tí yóò bu omi pa á.
7 Ẹ̀yin tí ẹ̀ sọ òdodo di ìkorò
tí ẹ sì gbé olódodo ṣánlẹ̀.
8 Ẹni tí ó dá ìràwọ̀ Pleiadesi àti Orioni
ẹni tí ó sọ òru dúdú di òwúrọ̀
tí ó sọ ọjọ́ dúdú di ìmọ́lẹ̀
ẹni tí ó wọ́ omi Òkun jọ pọ̀
tí ó sì rọ̀ wọ́n sí orí ilẹ̀
Olúwa ni orúkọ rẹ̀,
9 Ó fọ́n ìparun sí ìlú olódi
tí ó sì sọ àwọn ibùgbé àwọn ọmọ-aládé di ahoro.
10 Ìwọ kórìíra ẹni tí ń bá ni wí ní ẹnu ibodè
ó sì ń pẹ̀gàn ẹni tí ń sọ òtítọ́.
11 Ìwọ ń tẹ tálákà mọ́lẹ̀
o ń fi ipá gba ọkà lọ́wọ́ wọn.
Nítorí náà, ìwọ ti fi òkúta tí a gbẹ́ kọ́lé
ṣùgbọ́n ẹ kò sì ní gbé inú wọn,
Nítòótọ́ ìwọ ti gbin ọgbà àjàrà tí ó lẹ́wà.
Ìwọ kò ní mu wáìnì inú wọn.
12 Nítorí mo mọ iye àìṣedéédéé rẹ
mo sì mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tí tóbi tó.
Ìwọ ni olódodo lára, ìwọ sì ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀
o sì ń fi òtítọ́ du tálákà ní ilé ẹjọ́.
13 Àwọn ọlọ́gbọ́n máa ń dákẹ́ jẹ́ẹ́ ní àkókò wọ̀nyí,
nítorí búburú ni gbogbo ọjọ́.
14 Wá rere, má ṣe wá búburú
kí ìwọ ba à le yè.
Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun yóò wà pẹ̀lú rẹ.
Òun yóò sì wà pẹ̀lú rẹ bí ìwọ ṣe wí.
15 Kórìíra búburú kí o sì fẹ́ rere
dúró ní orí òtítọ́ ní ilé ẹjọ́
bóyá Olúwa Ọlọ́run alágbára
yóò síjú àánú wo ọmọ Josẹfu tó ṣẹ́kù.
16 Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wí:
“Ẹkún yóò wà ní àwọn òpópónà
igbe ìnira yóò sì wà ní àwọn gbàgede ìlú.
A ó kó àwọn àgbẹ̀ jọ láti sọkún
àti àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ láti pohùnréré ẹkún.
17 Ìpohùnréré ẹkún yóò wà ní gbogbo ọgbà àjàrà,
nítorí èmi yóò la àárín yín kọjá,”
ni Olúwa wí.
18 Ègbé ni fún ìwọ tí ó pẹ́
nítorí ọjọ́ Olúwa
kí ni ìwọ fi pẹ́ fún ọjọ́ Olúwa?
Ìmọ́lẹ̀ yóò di òkùnkùn ní ojú ọjọ́.
19 Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí ó sá fún kìnnìún,
tí ó padà wá bọ́ sí ẹnu àmọ̀tẹ́kùn.
Yóò dàbí ẹni tí ó wọ ilé rẹ̀ lọ
tí ó sinmi lé ògiri ilé rẹ̀
tí ejò sì bù ú ṣán.
20 Ǹjẹ́ ọjọ́ Olúwa kò ha ní ṣókùnkùn dípò kí ó ní ìmọ́lẹ̀?
Tí yóò sì ṣókùnkùn dúdú láìsí ìmọ́lẹ̀ kankan níbẹ̀.
21 “Mo kórìíra, mo kẹ́gàn àwọn àsè ẹ̀sìn in yín,
Èmi kò sì ní inú dídùn sí àpéjọ yín.
22 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ mú ẹbọ sísun àti ọrẹ ọkà wá.
Èmi kò ní tẹ́wọ́ gbà wọ́n.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ mú àṣàyàn ọrẹ àlàáfíà wá.
Èmi kò ní náání wọn.
23 Ẹ gbé ariwo orin yín sẹ́yìn!
Èmi kò ní fetísí ohun èlò orin yín.
24 Jẹ́ kí òtítọ́ sàn bí odò
àti òdodo bí ìsun tí kò lé è gbẹ!
25 “Àbí ẹ̀yin mú ẹbọ àti ọrẹ tọ̀ mí wá
ní ogójì ọdún ní aginjù ìwọ ilé Israẹli?
26 Ẹ̀yin ti gbé ibi ìrúbọ àwọn ọba yín sókè,
ibùgbé àwọn òrìṣà yín,
àní, ti àwọn òrìṣà yín tí ó níyì jùlọ,
èyí tí ẹ̀yin fi ọwọ́ ara yín ṣe.
27 Nítorí náà èmi yóò rán an yín lọ sí ìgbèkùn ní ìkọjá Damasku,”
ni Olúwa wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ọlọ́run alágbára.
6:1 Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ará rọ̀ ní Sioni
àti ẹ̀yin tí ẹ wà ní abẹ́ ààbò ní òkè Samaria
àti ẹ̀yin olókìkí orílẹ̀-èdè
tí ẹ̀yin ènìyàn Israẹli máa ń tọ̀ ọ́ wá.
2 Ẹ lọ Kalne kí ẹ lọ wò ó
kí ẹ sí tí ibẹ̀ lọ sí Hamati ìlú ńlá a nì.
Kí ẹ sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ Gati ní ilẹ̀ Filistini.
Ǹjẹ́ wọ́n ha dára ju ìpínlẹ̀ yín méjèèjì lọ?
Ǹjẹ́ a ha rí ilẹ̀ tó tóbi ju tiyín lọ bí?
3 Ẹ̀yin sún ọjọ́ ibi síwájú,
ẹ sì mú ìjọba òǹrorò súnmọ́ tòsí.
4 Ẹ̀yin sùn lé ibùsùn tí a fi eyín erin ṣe
ẹ sì tẹ́ ara sílẹ̀ ni orí àwọn ibùsùn
ẹyin pa èyí tí o dára nínú àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn yín jẹ
ẹ sì ń pa àwọn ọ̀dọ́ màlúù láàrín agbo wọn jẹ.
5 Ẹ̀yin ń lo ohun èlò orin bí i Dafidi
ẹ sì ń ṣe àwọn àpilẹ̀rọ àwọn ohun èlò orin.
6 Ẹ̀yin mu wáìnì ẹ̀kún ọpọ́n kan
àti ìkunra tí o dára jùlọ
ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò káàánú ilé Josẹfu tí ó di ahoro.
7 Nítorí náà, àwọn ni yóò lọ sí ìgbèkùn
pẹ̀lú àwọn tí ó ti kó lọ sí ìgbèkùn
àsè àwọn tí ń ṣe àṣelékè ni a ó mú kúrò.
8 Olúwa Olódùmarè ti búra fúnra rẹ̀, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun sì ti wí pé:
“Mo kórìíra ìgbéraga Jakọbu
n kò sì ní inú dídùn sí odi alágbára rẹ̀,
Èmi yóò sì fa ìlú náà lé wọn lọ́wọ́
àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀.”
9 Bí ọkùnrin mẹ́wàá bá ṣẹ́kù nínú ilé kan, àwọn náà yóò kú. 10 Bí ẹbí tí ó yẹ kí ó gbé òkú wọn jáde fún sínsin bá wọlé, bí o ba sì béèrè pé ǹjẹ́ ẹnìkan wa tí ó fi ara pamọ́ níbẹ̀, “Ǹjẹ́ ẹnìkankan wà lọ́dọ̀ yín?” tí ó bá sì dáhùn wí pé, “Rárá,” nígbà náà ni yóò wí pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́ àwa kò gbọdọ̀ dárúkọ Olúwa.”
11 Nítorí Olúwa tí pa àṣẹ náà,
Òun yóò sì wó ilé ńlá náà lulẹ̀ túútúú,
àti àwọn ilé kéékèèké sí wẹ́wẹ́.
12 Ǹjẹ́ ẹṣin a máa sáré lórí àpáta bí?
Ǹjẹ́ ènìyàn a máa fi akọ màlúù kọ ilẹ̀ níbẹ̀?
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti yí òtítọ́ padà sí májèlé
ẹ sì ti sọ èso òdodo di ìkorò.
13 Ẹ̀yin yọ̀ torí ìṣẹ́gun lórí Lo-Debari,
ẹ̀yin sì wí pé, “Ṣé kì í ṣe agbára wa ni àwa fi gba Karnaimu?”
14 Nítorí Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wí pé,
“Èmi yóò gbé orílẹ̀-èdè kan dìde sí ọ ìwọ Israẹli,
wọn yóò pọ́n yín lójú ní gbogbo ọ̀nà,
láti Lebo-Hamati, títí dé pẹ̀tẹ́lẹ̀ Arabah.”
7:1 Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè fihàn mí: Ó pèsè ọwọ́ eṣú lẹ́yìn ìgbà tí a kórè ìpín ọba, ní ìgbà ti èso ẹ̀ẹ̀kejì ń jáde bọ̀. 2 Nígbà tí wọ́n jẹ koríko ilẹ̀ náà mọ́ féfé nígbà náà ni mo gbé ohùn mi sókè pé, “Olúwa Olódùmarè, mo bẹ̀ ọ́, dáríjì! Báwo ni Jakọbu yóò ha ṣe lè dìde? Òun kéré jọjọ!”
3 Olúwa ronúpìwàdà nípa èyí.
“Èyí kò ni ṣẹlẹ̀,” ni Olúwa wí.
4 Èyí ni ohun ti Olúwa Olódùmarè fihàn mí: Olúwa Olódùmarè ń pè fún ìdájọ́ pẹ̀lú iná; ó jó ọ̀gbun ńlá rún, ó sì jẹ ilẹ̀ run. 5 Nígbà náà ni mo gbé ohùn mi sókè pé, “Olúwa Olódùmarè jọ̀wọ́ má ṣe ṣe é! Báwo ni Jakọbu yóò ha ṣe lè dìde? Òun kéré jọjọ!”
6 Olúwa ronúpìwàdà nípa èyí.
“Èyí náà kò ní ṣẹlẹ̀,” ni Olúwa Olódùmarè wí.
7 Èyí ni ohun tí ó fihàn mí: Olúwa dúró ní ẹ̀gbẹ́ odi ti a fi okùn ìwọ̀n mọ́, ti òun ti okùn ìwọ̀n tí ó rún ni ọwọ́ rẹ̀. 8 Olúwa sì bi mi pé, “Amosi, kí ni ìwọ rí?”
Mo dáhùn pé, “Okùn ìwọ̀n.”
Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Wò ó, Èmí ń gbé okùn ìwọ̀n kalẹ̀ láàrín àwọn Israẹli ènìyàn mi; Èmi kì yóò sì tún kọjá lọ́dọ̀ wọn mọ́.
9 “Ibi gíga Isaaki wọ̀n-ọn-nì yóò sì di ahoro
àti ibi mímọ Israẹli wọ̀n-ọn-nì yóò di ahoro.
Èmi yóò sì fi idà dìde sí ilé Jeroboamu.”