Ìṣọ̀tẹ̀ Absalomu (continued)

1027 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Saamu 55

Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Maskili ti Dafidi.

1 Fi etí sí àdúrà mi, Ọlọ́run,

má ṣe fi ojú pa ẹ̀bẹ̀ mi rẹ́:

2 gbọ́ mi kí o sì dá mi lóhùn.

Èrò mi ń dà mí láàmú, èmi sì ń pariwo.

3 Sí ohùn àwọn ọ̀tá ni,

nítorí igbe àwọn ènìyàn búburú;

nítorí wọ́n mú ìjìyà wá sórí mi,

wọ́n sì kẹ́gàn mi nínú ìbínú wọn.

4 Ọkàn mi wà nínú ìrora pẹ̀lú;

ẹ̀rù ikú kọjú ìjà sí mi.

5 Ìbẹ̀rù àti ìwárìrì wa sí ara mi;

ìbẹ̀rù ti bò mí mọ́lẹ̀.

6 Èmi sọ pé, “Èmi ìbá ní ìyẹ́ bí àdàbà!

Èmi ìbá fò lọ kí n sì sinmi.

7 Èmi ìbá sálọ, jìnnà réré,

kí ń sì dúró sí aginjù;

8 èmi ìbá yára lọ́ si ibùgbé mi ní ibi ààbò,

jìnnà kúrò nínú ìjì àti ẹ̀fúùfù líle.”

9 Da àwọn ẹni búburú láàmú, Olúwa, da ahọ́n wọn rú,

nítorí èmi rí ìwà agbára àti ìjà ní ìlú náà.

10 Ọ̀sán àti òru ni wọ́n fi ń rìn gbogbo odi kiri;

ìwà ìkà àti èébú wà láàrín rẹ̀.

11 Ìwà búburú ń bẹ ní àárín rẹ̀;

ẹ̀tàn àti èké kò kúrò ní ìgboro rẹ̀.

12 Tí ọ̀tá bá tàbùkù mi,

èmi yóò fi ara mọ́ ọn;

tí ọ̀tá bá gbé ara rẹ̀ ga sí mi,

èmi ìbá sá pamọ́ fún un.

13 Ṣùgbọ́n tí ó bá ṣe ìwọ, ọkùnrin bí ẹgbẹ́ mi,

ẹlẹgbẹ́ mi, àti ọ̀rẹ́ tí ó súnmọ́ mi,

14 pẹ̀lú ẹni tí èmi ti jẹ ìgbádùn adùn ìdàpọ̀,

bí a ṣe ń rìn pẹ̀lú àwùjọ ní ilé Ọlọ́run.

15 Kí ikú kí ó dé bá wọn,

kí wọn ó lọ láààyè sí isà òkú,

jẹ́ kí wọn ó sọ̀kalẹ̀ sí ibojì pẹ̀lú ìpayà,

nítorí tí ìwà búburú ń bẹ ní ibùjókòó wọn, àti nínú wọn.

16 Ṣùgbọ́n èmi pe Ọlọ́run;

Olúwa yóò sì gbà mí.

17 Ní alẹ́, ní òwúrọ̀ àti ní ọ̀sán

èmi sọkún jáde nínú ìpọ́njú,

o sì gbọ́ ohùn mi.

18 Ó rà mí padà láìléwu

kúrò nínú ogun tí ó dìde sí mi,

nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó dìde sí mi.

19 Ọlọ́run yóò gbọ́, yóò sì pọ́n wọn lójú àní,

ẹni tí ó ti jókòó láti ìgbàanì Sela,

nítorí tí wọn kò ní àyípadà,

tí wọn kò sì bẹ̀rù Ọlọ́run.

20 Ọ̀rẹ́ mi yìí ti dalẹ̀ èmi ọ̀rẹ́ rẹ̀;

ó ti ba májẹ̀mú rẹ̀ jẹ́.

21 Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ kúnná ju òrí-àmọ́,

ṣùgbọ́n ogun wà ni àyà rẹ̀;

ọ̀rọ̀ rẹ̀ fẹ́lẹ́ ju òróró lọ,

ṣùgbọ́n idà fífàyọ ní wọn.

22  Gbé ẹrù rẹ lọ sí ọ̀dọ̀ Olúwa

yóò sì mú ọ dúró;

òun kò ní jẹ́ kí olódodo ṣubú.

23 Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni yóò mu àwọn ọ̀tá mi

wá sí ihò ìparun;

àwọn ẹni tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ àti ẹni ẹ̀tàn,

kì yóò gbé ààbọ̀ ọjọ́ wọn.

Ṣùgbọ́n fún èmi, èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ.

Saamu 4–5

Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu ti Dafidi.

1 Dá mi lóhùn nígbà tí mo bá pè ọ́,

ìwọ Ọlọ́run òdodo mi.

Fún mi ní ìdáǹdè nínú ìpọ́njú mi;

ṣàánú fún mi, kí o sì gbọ́ àdúrà mi.

2 Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó, ẹ̀yin ọmọ ènìyàn, tí ẹ ó ṣe sọ ògo mi di ìtìjú?

Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó, tí ẹ̀yin yóò ṣe fẹ́ràn ìtànjẹ àti tí ẹ̀yin yóò fi máa wá ọlọ́run èké?

3 Ṣùgbọ́n kí ẹ mọ̀ pé, Olúwa ti ya ẹni olódodo sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀;

Olúwa yóò gbọ́ nígbà tí mo bá pè é.

4  Ẹ bínú ẹ má ṣe ṣẹ̀,

nígbà tí ẹ bá wà lórí ibùsùn yín,

ẹ bá ọkàn yín sọ̀rọ̀, kí ó sì dákẹ́ jẹ́.

5 Ẹ rú ẹbọ òdodo

kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.

6 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló ń béèrè pé, “Ta ni yóò ṣe rere fún wa?”

Olúwa, jẹ́ kí ojú rẹ mọ́lẹ̀ sí wa lára,

7 Ìwọ ti fi ayọ̀ púpọ̀ kún ọkàn mi

ju ìgbà tí hóró irúgbìn àti wáìnì tuntun wọ́n pọ̀ fún mi lọ.

8 Èmi yóò dùbúlẹ̀, èmi ó sì sùn ní àlàáfíà,

nítorí ìwọ nìkan, Olúwa,

ni o mú mi gbé láìléwu.

Fún adarí orin. Fún ohun èlò orin fífọn. Saamu ti Dafidi.

5:1 Fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, Olúwa,

kíyèsi àròyé mi.

2 Fi etí sílẹ̀ sí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́,

ọba mi àti Ọlọ́run mi,

nítorí ìwọ ni mo gba àdúrà sí.

3 Ní òwúrọ̀, Olúwa, ìwọ yóò gbọ́ ohùn mi;

ní òwúrọ̀, èmi yóò gbé ẹ̀bẹ̀ mi sí iwájú rẹ̀

èmi yóò sì dúró ní ìrètí.

4 Nítorí ìwọ kì í ṣe Ọlọ́run tí ó ní inú dídùn sí búburú;

bẹ́ẹ̀ ni ẹni ibi kò le è bá ọ gbé.

5 Àwọn agbéraga kò le è dúró

níwájú rẹ̀.

Ìwọ kórìíra gbogbo àwọn aṣebi;

6 ìwọ yóò pa àwọn tí ń ṣe èké run.

Apani àti ẹni ẹ̀tàn ènìyàn

ni Olúwa yóò kórìíra.

7 Ṣùgbọ́n èmi, nípa títóbi àánú rẹ̀,

èmi yóò wá sínú ilé rẹ̀;

ní tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ni èmi yóò tẹríba

sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀.

8 Tọ́ mi, Olúwa, nínú òdodo rẹ,

nítorí àwọn ọ̀tá mi,

mú ọ̀nà rẹ tọ́ níwájú mi.

9  Kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ẹnu wọn tí a lè gbàgbọ́;

ọkàn wọn kún fún ìparun.

Ọ̀nà ọ̀fun wọn ni isà òkú tí ó ṣí sílẹ̀;

pẹ̀lú ahọ́n wọn ni wọ́n ń sọ ẹ̀tàn.

10 Dá wọn lẹ́bi Ọlọ́run!

Jẹ́ kí rìkíṣí wọn jẹ́ ìṣubú wọn.

Lé wọn jáde nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ wọn,

nítorí wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ.

11 Ṣùgbọ́n, jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó sádi ọ́ kí ó yọ̀;

jẹ kí wọn máa kọrin fún ayọ̀ títí.

Tan ààbò rẹ sórí wọn,

àti àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ yóò máa yọ̀ nínú rẹ.

12 Dájúdájú, Olúwa, ìwọ bùkún olódodo;

ìwọ fi ojúrere rẹ yí wọn ká bí asà.